Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Latigba ti wọn ti mu Sunday Igboho ti mọle sorilẹ-ede Olominira Bẹnnẹ, koda pẹlu bi wọn ṣe n gbe e lọ sile-ẹjọ to, ibẹru to wa lọkan ọpọ eeyan ni Naijiria ni pe njẹ ijọba Naijiria yii ko ni i fipa gbe e wale bayii lati fiya jẹ ẹ. Ṣugbọn agba ninu awọn lọọya to n gbẹjọ ro fun Igboho, Ọmọwe Maliki Ṣẹgun Falọla, lati orilẹ-ede France ti ni kawọn eeyan fọkan balẹ, ko sẹni kan to lagbara lati fipa gbe ajijagbara naa wa si Naijiria.
Ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ni Amofin Falọla sọ eyi di mimọ pẹlu awọn ọrọ mi-in nipa Sunday Igboho, iyẹn nigba ti AKEDE AGBAYE ṣabẹwo sorilẹ-ede Olominira Benin lati ri lọọya naa. Nigba to n dahun ibeere nipa bi wọn ṣe ni ijọba Naijiria fẹẹ fi ipa tabi ọgbọn alumọkọrọyi gbe e wọ Naijiria, ọkunrin to n lewaju ninu awọn lọọya mẹsan-an ti Igboho gba sọ pe ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ko ni agbara kankan labẹ ofin lati gbe Igboho wa si Naijiria, nitori ọrọ ọkunrin naa ti kuro ni ti Naijiria ati ti Bẹnnẹ nikan.
O ni gbogbo agbaye lo n tẹle iṣẹlẹ yii, aṣẹ rẹ ki i ṣe ti ilu kan ṣoṣo.
Nipa idi ẹ ti wọn ko ṣe fi i silẹ lọjọ Aje ti wọn gbọ ẹjọ rẹ ni kootu ni Bẹnnẹ, Amofin Falọla sọ pe Igboho ko ṣee fi silẹ bẹẹ, nitori eeyan to n wa si kootu lọjọ to ba fẹẹ jẹjọ n wọ ẹgbẹrun kan. Lati waa tu u silẹ pe ko maa lọ tabi pe ki wọn gba beeli rẹ, o ni yoo da wahala silẹ, wahala ti yoo mu ẹmi lọ ni pẹlu, nitori bawọn ololufẹ rẹ yoo ṣe maa fa a lawọn ti inu wọn ko dun naa yoo fẹẹ yọwọ tiwọn. O ni idi niyẹn ti adajọ fi ni ki wọn ṣi fi i satimọle na.