Iya buruku lawọn DSS fi n jẹ awọn eeyan Sunday Igboho latimọle, ounjẹ buruku ni wọn n fun wọn jẹ- Lọọya

Faith Adebọla

Oriṣiiriṣii iya ajẹkudorogbo ati ipọnju ni wọn lawọn ẹṣọ agbofinro fi n jẹ awọn eeyan ti wọn mu sahaamọ wọn l’Abuja, nigba ti wọn lọọ ṣakọlu sile Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho lọjọsi.

Lọọya kan to ṣoju awọn afurasi mejila tijọba n ba ṣẹjọ lọwọ naa, Amofin Pẹlumi Ọlajẹngbesi lo taṣiiri ọrọ yii funleeṣẹ iweeroyin PUNCH lopin ọsẹ to kọja yii, nigba to n sọrọ lori ibi tọrọ de duro lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọlajẹngbesi ni ipo ti ko ba ara mu lawọn ti wọn fi sahaamọ DSS yii wa, o loun ṣabẹwo sibẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, tori latẹyinwa, fun bii ọsẹ mẹrin ti wọn ti mu wọn satimọle, wọn o jẹ koun foju kan wọn, wọn o si jẹ ki mọlẹbi wọn kankan foju gan-an-ni wọn.

O ni yatọ si pe wọn ko ri ounjẹ gidi kan jẹ, epo ti wọn fi n sebẹ fun wọn ko yatọ si ọili ti wọn n rọ si ẹnjinni mọto, iyẹn ‘engine oil’, ni wọn fi n se ọbẹ ti wọn n fun wọn jẹ, wọn ni ki wọn maa fi ọbẹ naa jẹ ẹba tabi Fufu, awọn eeyan naa ko si le kọ, tori ko si ounjẹ mi-in, wọn o si jẹ kẹnikẹni ṣeranwọ fun wọn.

Ọlajẹngbesi ni ọpọ awọn ti wọn fi sahaamọ naa ni wọn ti n ṣaisan, igbẹ gbuuru, kokoro ara ati ikọ si ti n ba wọn finra gidi, o ni ounjẹ ipọnju ti wọn n pese fawọn eeyan naa wa lara ohun to ṣokunfa ailera wọn yii.

Lọọya naa sọ pe oun atawọn agbẹjọro meji mi-in tawọn jọ n ṣiṣẹ lori igbẹjọ wọn ṣepade pẹlu mẹrin lara awọn afurasi naa, ohun tawọn si ri ya awọn lẹnu gidi, o ni koda, eeyan ko gbọdọ fi iru iya ti wọn n fi jẹ awọn onibaara awọn yii jẹ ẹranko, ka ma ṣẹṣẹ sọ pe eeyan onile ọlọna bii tiwọn.

“Ẹ jẹ ki n sọ bọrọ ṣe ri gan-an, ipo ti wọn wa yii jẹ apẹẹrẹ iwa ika, titẹ ẹtọ ọmọlakeji loju ati fifoju ẹni gbolẹ to buru jai.

Ori ilẹ lasan ni wọn n sun, alupamokuu si ni wọn maa n lu wọn, ti wọn ba fi le ṣaroye pe ara awọn o ya, ki wọn too pese itọju iṣegun fun wọn.

Afi bii ẹni pe Lady K, ti ṣẹ wọn lọtọ ni, wọn lu u bii ẹni lu aṣọ ofi, wọn ti ṣe e leṣe lẹṣẹ osi, ọgbẹ nla ni wọn da si i lẹsẹ, inu irora nla lo wa bi mo ṣe n sọ yii. Aṣọ kan ṣoṣo to wa lọrun ẹ latọjọ ti wọn ti mu un pẹlu awọn to ku naa lo wọ, wọn o jẹ ko paarọ ẹ, niṣe lo maa n kako to ba fẹẹ sun lalẹ, tori sẹẹli ti wọn fi wọn si ko gba ero to wa nibẹ.

Ọpọ ninu wọn lo ti ni aisan ẹjẹ riru, gẹgẹ bii alaye ti wọn ṣe fun wa nileewosan alabọọde SSS to wa nibẹ. Bi wọn ba jẹun tan, oju-ẹsẹ naa ni wọn n lọọ yagbẹ, tori ounjẹ inira ni wọn n fun wọn jẹ.

Eeyan o tiẹ gbọdọ ṣe’ru nnkan ti wọn n ṣe fun wọn yii fun ẹran ọsin lasan, dipo eeyan ẹlẹran ara. Iwa bi wọn ba le ku ki wọn ku ni wọn n hu si wọn. Ṣugbọn ka too kuro nibẹ, a fi wọn lọkan balẹ pe wọn maa jade, ki wọn mọkan le, ki wọn si fara da a. A si jẹ ki wọn mọ nipa awọn igbesẹ ti a n gbe ati bile-ẹjọ ṣe n boju to ọrọ wọn.”

Tẹ o ba gbagbe, oru mọju Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ ki-in-ni, oṣu keje yii, lawọn ẹṣọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ọhun ti lọọ ṣakọlu sile Sunday Igboho to wa laduugbo Sọka, n’Ibadan, ti wọn paayan meji, wọn ko awọn mẹtala lọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ja ọkan lara wọn ju silẹ l’Ekiti, bi wọn ṣe n lọ. Latigba naa si lawọn eeyan yii ti wa lahaamọ wọn, ti wọn si kọ lati gbe wọn lọ sile-ẹjọ tabi tu wọn silẹ.

Awọn eeyan naa ni wọn pe ijọba apapọ, ileeṣẹ DSS, ati ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lẹjọ sile-ẹjọ giga kan niluu Abuja, wọn fẹ kile-ẹjọ paṣẹ itusilẹ wọn, kijọba si sanwo itanran fun ahamọ ti wọn fi wọn si ati awọn ẹtọ wọn ti wọn tẹ mọlẹ.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ni igbẹjọ waye kẹyin lori ọrọ naa, ṣugbọn ileeṣẹ DSS kuna lati ko awọn afurasi naa wa sile ẹjọ.

Eyi lo mu ki Adajọ Obiora Egwuata sun igbẹjọ to kan si ọjọ Aje, Mọnde ọjọ keji, oṣu kẹjọ, o si tun paṣẹ pe dandan ni kileeṣẹ DSS ko awọn eeyan yii wa si kootu, dandan si ni ki wọn fawọn lọọya wọn laaye lati ba onibaara wọn ti wọn n ṣoju fun sọrọ bo ṣe yẹ.

Leave a Reply