Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ti i fi ọrọ mulẹ pe ikọ agbebọn ati ajinigbe to ji awọn akẹkọọ ileewe Olabisi Onabanjo University gbe n beere owo, ALAROYE gbọ pe awọn eeyan naa ti ranṣẹ si ẹbi awọn ọmọ meji yii, aadọta miliọnu (50m) ni wọn si lawọn fẹẹ gba gẹgẹ bii owo itusilẹ wọn.
Orukọ awọn akẹkọọ meji naa ni Adeyẹmọ Oluwaṣeun to wa nipele kẹta lẹka imọ nipa igbo kijikiji ati Oyefule Oluwatosin toun naa wa nipele kẹta lẹka imọ ọgbin.
Nnkan bii aago mẹsan-alẹ ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, ni wọn ji wọn gbe niwaju ile wọn to wa lagbegbe Olowu, Igbole Aibo, l’Ayetoro.
Ibọn ni awọn agbebọn naa bẹrẹ si i yin lakọlakọ ki wọn too ji awọn ọmọge meji yii gbe, ko si si nnkan mi-in mọ lẹyin naa ju pe wọn gbe wọn sa lọ.
Ọmọbinrin kan to n ta kaadi ipe lọpọ yanturu ni wọn ni awọn ajinigbe naa wa wa sagbegbe ọhun, oun gan-an ni wọn feẹ ji gbe, ṣugbọn wọn ko raaye de ile to n gbe, bi wọn ṣe n bọ ti wọn ri awọn meji yii nita ile wọn ni wọn gbe wọn ju sọkọ pẹlu tulaasi, ni wọn ba wa wọn lọ raurau.
Lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ti i ṣe ọjọ keji iṣẹlẹ naa ti ALAROYE pe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ọkunrin naa sọ pe ọga ọlọpaa ẹkun Ayetoro lo lewaju lasiko ti a n pe oun naa, ti awọn n fọ gbogbo agbegbe naa kiri. Oyeyẹmi sọ pe gbogbo agbegbe naa pata lawọn ti gba kankan bayii, ko si aaye irinkurin kan nibẹ, bẹẹ lawọn n ṣiṣẹ takuntakun lati kẹẹfin awọn amookunṣika naa ati lati ri awọn ọmọ yii gba walẹ.
Bakan naa ni ọga to n ri si ọrọ to ba jọ bii eyi ni yunifasiti naa, Ọgbẹni Niyi Oduwọle, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni ohun to ba ni lọkan jẹ gidi niṣẹlẹ yii, ṣugbọn awọn alasẹ ileewe naa ti n sa gbogbo ipa wọn lati ri awọn ọmọ meji naa jade.
CP Edward Ajogun, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun naa ti paṣẹ pe afi ki wọn wa awọn ọmọ naa ri, nitori ẹ ni ikọ to n ri si ijinigbe ninu ọlọpaa ṣe ti wa nita bayii, ti wọn n wa gbogbo ọna lati ri awọn akẹkọọ naa gba pada.