Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Akolo ajọ ẹsọ alaabo, ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ni ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelaaadọta kan, Michael Adedayọ, ṣi wa bayii fẹsun pe o fi aadọta Naira tan ọmọ to n ta pọfupọọfu to jẹ ọmọ ọrẹ timọtimọ rẹ, ọmọde binrin ẹni ọdun mẹrinla, Abdul Fatai Hajarat, to si fipa ba a lo pọ lagbegbe Ori Oke, Ẹlẹkọyangan, niluu Ilọrin.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lo ti ṣalaye pe baba ọhun fi aadọta Naira tan ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrinla, Abdulfatai Hajarat, to jẹ ọmọ ọrẹ timọtimọ rẹ ti wọn jọ n gbe ile kan naa, to si fipa ba a lo pọ. O tẹsiwaju pe pọfupọọfu ni ọmọdebinrin yii n ta, ko si le ma kiri ọja de sọọbu Michael. Lasiko to kiri lọ sibẹ lo tan an wọle, to si fipa ba a lo pọ. Bakan naa lo ti jẹwọ pe loootọ loun fipa ba ọmọ ọhun lo pọ, bẹẹ ni ki i ṣe ẹẹkan.
Eyi to tun fara pẹ ẹ ni ti ọkunrin kan, Tajudeen Hammed, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ti ajọ naa tun mu fẹsun pe o fi tipatipa ko ibalopọ fun ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrindinlogun ti orukọ rẹ n jẹ Isiaka Hawau.
Iwadii ti bẹrẹ lẹkun-un-rẹrẹ lori awọn iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Makinde Ayinla si ti sọ pe awọn yoo fi oju awọn afurasi naa ba ile-ẹjọ laipẹ.