Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ yii, EFCC, ti mu aafaa meji ati awọn ọmọ yahoo-yahoo marun-un ni otẹẹli kan niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, fun ẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara.
Awọn aafaa meji tọwọ tẹ ni Ahmed Abdulkadir, lati ijọba ibilẹ Iwo, nipinlẹ Ọsun, ati Abdullateef Ajibọla, lati ilu Babanlomọ, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara. Awọn ọmọ yahoo tọwọ tẹ ni Tọmiwa Kingsley, agunbanirọ to n sin ijọba nijọba ibilẹ Pategi, ni Kwara; Mujeeb Jatto, lati ijọba ibilẹ Ọffa, ni Kwara; Adebayọ Sofiullah, lati ilu Babanlomọ, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara, Okeke Wisdom, lati ipinlẹ Anambra ati Festus Ogeleka, lati ipinlẹ Delta.
Ajọ EFCC sọ pe awọn aafaa mejeeji ni wọn n ba awọn ọmọ yahoo naa ṣe oogun ninu otẹẹli ti wọn ti ko wọn, ti ajọ naa si sọ pe lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii, awọn afurasi naa yoo foju ba ile-ẹjọ.