Ọwọ ọlọpaa tẹ ọkunrin to ko oogun oloro pamọ sinu bọneẹti mọto

jọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni awọn oṣiṣẹ awọn kan gba idi oogun oloro mọkanlelogun (21)  ti wọn fura si pe o jẹ igbo lọwọ ọkunrin kan lagbegbe Ọgba, nipinlẹ naa.

Lasiko tawọn agbofinro yii fọn si titi lati ṣe duro-n-yẹ-ọ-wo fawọn awakọ nitosi ile itura Excellence Hotel, to wa ni Aguda, Ọgba, ni awọn ọlọpaa teṣan Area G ti ri oogun oloro naa ti wọn gbe pamọ sinu imu ọkọ (bonnet) Sienna ti nọmba ara rẹ jẹ, BEN 883 LW.

 

 

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe lọgan lawọn agbofinro fi panpẹ ofin gbe awakọ naa torukọ ẹ n jẹ Kalu Orji, bẹẹ ni Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Abiọdun Alabi, ti paṣẹ pe ki wọn gbe ẹjọ naa lọ si olu ileeṣẹ wọn fun iwadii to peye.

Agbẹnusọ ọlọpaa l’Ekoo, Benjamin Hundenyin, sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade to fi sita.

Ninu ọrọ ẹ lo ti ni, “Awọn agbofinro teṣan ọlọpaa Area G, to wa lagbegbe Ọgba, nipinlẹ Eko, ti gba oogun oloro to wa ninu idi lọna mọkanlelogun, eyi ti wọn fura si pe o ṣee ṣe ko jẹ igbo lọwọ afurasi kan. Oogun oloro yii ni wọn bo daadaa, ti wọn si tọju pamọ si imu ọkọ Sienna pẹlu nọmba idanimọ BEN 883 LW, ti Ọgbẹni Kalu Orji, ẹni ọdun mejilelọgbọn to wa lati agbegbe Angle 90, ilu Auchi, nipinlẹ Edo.

 

 

“Ṣugbọn nigba ti ori maa ta ko Orji, awọn ọlọpaa agbegbe Area G gbera, o di irona lati bẹrẹ si i yẹ ọkọ wo yẹbẹyẹbẹ loju popo lọsan-an ọjọ naa, nibẹ ni wọn ti da ọkọ Sienna to n wa yii duro ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ku ogun iṣẹju lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, lagbegbe Aguda, itosi Excellence Hotel, Ọgba.”

 

 

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ EkoAbiọdun Alabi, ti paṣẹ pe ki wọn ko ẹjọ naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fun iwadii to gbopọn. Bakan naa lo fi awọn araalu lọkan balẹ pe awọn ko ni yẹsẹ lori adehun awọn lati ri i daju pe awọn daabo bo ẹmi ati dukia wọn. Bẹẹ lo fi kun un pe awọn ko ni sinmi ninu akitiyan awọn lati gbogun ti aṣilo ati ilokulo oogun nipinlẹ Eko”.

Leave a Reply