Ki Atiku ma darukọ mi bi wọn ba fẹyin rẹ janlẹ lasiko ibo aarẹ ọdun to n bọ – Wike

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti sọ fun oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ PDP, Alaaji Atiku Abubakar, lati ma ṣe di ẹbi ọrọ ru oun nigba to ba pada padanu ninu ibo apapọ ọdun 2023 to n bọ lọna.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni gomina ọhun sọrọ yii lasiko ti wọn n ṣi awọn ile tuntun ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa, eyi ti olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, ba wọn tukọ rẹ.

Wike fa Atiku leti lati ṣọra fawọn to yi i ka, to ba mọ pe oun fẹẹ jawe olubori ninu ibo ọdun to n bọ, nitori wọn le mu ko fidi rẹmi ninu ibo aarẹ.

Gomina Wike to jẹ pe ede aiyede wa laarin oun ati Atiku lọwọlọwọ bayii sọ pe awọn kan n gbọn tẹle e kiri nigba to jẹ pe bi wọn yoo ṣe gbegba oroke ninu ibo ọdun to n bọ lo yẹ ko mumu laya wọn.

O ni, “Ohun to yẹ ko jẹ afojusun gbogbo ẹni to nifẹẹ ẹgbẹ oṣelu PDP denudenu, to si n fẹ aṣeyọri wọn niyi. Bi o ṣe fẹẹ wọle ibo loun to yẹ ki ẹ maa sọrọ le lori. Gbogbo awọn ti Atiku n ko kiri yii o ṣe e lanfaani kankan. Gbogbo igbesẹ wọn ni bi Atiku ko ṣe ni wọle ibo, ṣugbọn to ba ti jẹ ohun ti wọn fẹ niyẹn, mo fi Ọlọrun sin wọn “.

“Ẹ ṣaa ri i pe mi o sọrọ. Iṣẹ mi ni mo n ṣe, ẹ fi mi silẹ ki n maa ṣiṣẹ mi lọ. Gbogbo awọn ti wọn n ba a kọ nnkan oriṣiiriṣii, paapaa ju lọ lori ẹrọ ayelujara, ko le ni ki o wọle. Atiku, o jẹ yaa sọ fawọn ti wọn wa pẹlu ẹ l’Abuja lati dari wale waa polongo ibo fun ọ. Ẹ fi Wike lọrun silẹ, o to gẹẹ”.

Nigba to n tẹsiwaju, Wike wẹ ara ẹ mọ ninu ẹsun ti wọn fi kan an pe o n ṣe aṣemaṣe kan lati da ẹgbẹ wọn ru.

O ni, “Awọn eeyan ti pe mi ni aimọye igba lonii, ọrọ pe mo si wọ Atiku lọ sileẹjọ ni wọn n ba mi wi fun. Mo waa fẹ sọ ọ ni gbangba gbangba pe ti n ba tiẹ nilo lati lọ si kootu, mo le lọ sile ẹjọ, ṣugbọn mi o lọ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

 

 

“Lanaa ode yii naa, wọn ni mo yọ gbogbo asia ẹgbẹ oṣelu PDP to wa nile ijọba ipinlẹ Rivers danu. Ṣugbọn mo kan ni lati sọ awọn nnkan wọnyi fawọn ọmọ Naijiria lati mọ pe mo ti ṣe ẹnu mi ni gbọlagun, mo ti dakẹ jẹẹ, bẹẹ lọwọ mi di lati bii ọjọ meloo yii gẹgẹ bi mo ṣe n ṣe ojuṣe mi fun ẹgbẹ mi lati rẹsẹ walẹ, ki wọn si gbegba oroke ninu eto idibo ipinlẹ yii.

“Ṣugbọn mo fẹ ki oludije dupo aarẹ lẹgbẹ wa funra ẹ mọ pe awọn ẹmẹwa ẹ ni wọn n ṣe gbogbo nnkan yii. Ka kegbajare faye gbọ pe awọn ni wọn wa nidii ọrọ yii, ero wọn si ni pe awọn yoo fi ba mi lorukọ jẹ, ṣugbọn ala ti ko le ṣẹ ni.

Mo si ti sọ fun ẹni to n dupo funra ẹ pe atiwọle ibo tabi ijakulẹ rẹ wa lọwọ awọn eeyan to n tẹle e kiri, eeyan to ba mọ mi daadaa maa mọ pe ti mo ba fẹẹ lọ si kootu ni, laarin ọsẹ meji ta a ti dibo abẹle ni ma a ti lọ, nitori ọrọ ki eto idibo too waye ni, bẹẹ si ree, eeyan o le gba ile-ẹjọ lọ mọ lẹyin ọsẹ meji.

“Olubadamọran lori eto idajọ lẹgbẹ waa pe mi, o loun mọ pe awọn nnkan ti ko tọ n ṣẹlẹ. Ṣugbọn nitori oun mọ mi daadaa, nitori mi o le lo ẹnikẹni ninu awọn lọya yẹn, mi o tilẹ mọ awọn lọya ti wọn n sọ ọhun ri”.

Wike sọrọ siwaju, o ni lasiko eto idibo gbogboogbo ọdun 2019, gbogbo awọn ti wọn lawọn nifẹẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lapa Guusu Guusu orilẹ-ede yii ni wọn bẹgi dina ati wọle ẹgbẹ ọhun lapa ọdọ awọn nibẹ.

O ni kaka ki awọn gomina ọhun waa pamọpọ, ki wọn forikori lori bi wọn yoo ṣe jawe olubori ninu ibo ọdun 2023, niṣe ni wọn n fakoko wọn ṣofo nipa gbigbe ogun ti oun.

“Nigba ti n ba ri awọn eeyan ti wọn n sọrọ nipa PDP lonii, mo maa n bi ara mi leere pe ki lo n ṣẹlẹ laye. Ni iha Guusu Guusu nibi, gbogbo wọn ni wọn ti da wa, ti wọn ja wa kulẹ. Koda gan-an, Aarẹ Muhammadu Buhari o ba ma wọle nitori o loju ibi ti ọwọja rẹ de”.

Leave a Reply