Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Latari bi awọn ọdọ kan ṣe dana sun aafin ọba ilu Iree, nipinlẹ Ọṣun, awọn afọbajẹ ilu naa ti naka aleebu si awọn ọmọọba pe awọn ni eku ẹda to da wahala naa silẹ, bẹẹ ni awọn ọmọọba naa n sọ pe awọn afọbajẹ ni ọdada ti ko fẹ kilu toro.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila yii, ni wahala kan bẹ silẹ niluu naa, ti awọn ọdọ kan ti inu n bi si dana sun abala aafin Aree, ṣugbọn ko si kabiesi laafin lasiko iṣẹlẹ naa.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Ọsọlọ ti ilu Iree, Oloye Sọbalaje Ajao, ṣalaye pe bi awọn ileeṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ (DSS), ṣe mu ọkan lara awọn afọbajẹ, Oloye Saliu Atoyebi to jẹ Aogun ti ilu Iree, lo fa a ti awọn ọdọ ilu naa fi fabinu yọ.
Oloye Ajao fẹsun kan kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ tẹlẹ nipinlẹ naa, Ọnarebu Bayọ Adeleke, to ni oun lo ni ki awọn SSS waa gbe baba naa.
O fi kun ọrọ rẹ pe pẹlu aṣẹ Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, pe ki ẹnikẹni ma ṣe duro laafin naa, ki awọn ọlọpaa si gbelẹkun ibẹ ti, sibẹ, Ọba Rapheal Olupọnnle ko kuro laafin.
O waa ke si ijọba pe ki wọn ri i pe aṣẹ naa fẹsẹ mulẹ niluu Iree, nitori ki i ṣe ilana yiyan ọba niluu naa ni wọn gba yan Ọba Pọnnle.
Ṣugbọn Ọnarebu Adeleke ni irọ funfun balau ni nnkan ti awọn afọbajẹ naa n sọ. O ni awọn kan ti Oloye Atoyebi ba lorukọ jẹ ni wọn kọwe lọ sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ, ti awọn yẹn si fi pampẹ ofin gbe e lati le fidi ọrọ rẹ mulẹ.
Adeleke ni ṣe lawọn eeyan naa mọ-ọn-mọ fẹẹ da wahala silẹ lati le jẹ ko da bii ẹni pe wahala wa lori ọrọ ọba ti wọn ṣẹṣẹ yan niluu naa, eleyii ti ko ri bẹẹ rara, nitori gbogbo awọn ọlọmọọba ni wọn fọwọ si iyansipo Ọba Pọnnle.
Bakan naa, Ọmọọba Gbemiga Ọlatunji, ẹni to sọrọ lorukọ awọn ọmọọba ile Oyekun, Larọoye, Iyọọnla, Ojo Ayagaga ati Olubọnku ṣalaye pe bi wọn ṣe mu Aogun ko ni i ṣe pẹlu ọrọ ọba rara, o ke si awọn araalu lati ma ṣe faaye gba awọn janduuku ti wọn ti pinnu lati da omi alaafia ilu naa ru.
Ọlatunji sọ siwaju pe ti awọn eeyan naa ba n ja fun mimu Aogun, ki lo kan didana sun aafin ilu nibẹ, ki lo si fa a ti awọn janduku fi n wọle lọọ ṣe awọn araalu ti wọn ko mọ nnkan kan leṣe? O ni bi wọn ṣe ṣa awọn kan laake, ni wọn ba ọpọlọpọ dukia jẹ, ti wọn si na awọn mi-in lalubami.
Gbogbo awọn ọmọọba ti wọn ba ALAROYE sọrọ ni wọn bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, wọn ni ko ṣẹlẹ ri niluu Iree, wọn waa ke si ijọba Gomina Ademọla Adeleke lati ma ṣe gbọ ahesọ kankan nipa ilu Iree, nitori alaafia wa, ko si si wahala kankan latigba ti Ọba Olupọnnle ti gun ori-itẹ awọn baba nla rẹ.