Ọlawale Ajao, Ibadan
Aago mẹrin, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, ni wọn yoo sinku Ọba Adeyẹmi to waja si ibi ti wọn maa n sin oku awọn ọba Ọyọ si ni adugbo Baara, niluu Ọyọ.
Ni nnkan bii aago mejila ku diẹ ni Imaamu agba ilu Ọyọ, Sheik Mos’ud Ajokideru, kirun si Alaafin Ọyọ to darapọ mọ awọn baba nla rẹ yii, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, lara niwaju aafin Aganju, nibi ti awọn eeyan pejọ si lati ṣadura fun ọba alaye to waja yii, iyẹn lẹyin ti wọn ti ṣe gbogbo etutu to yẹ ni ilana aṣa ati iṣe Yoruba.
Bakan naa ni awọn ọmọ ọba alaye yii wa nibi ti wọn ti kirun si i lara yii.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin yii, ni Alaafin papoda ni ọsibitu ile ẹkọ giga Afẹ Babalọla to wa niluu Ado-Ekiti. Oju-ẹsẹ ni wọn si ti gbe oku ọba alaye yii pada si aafin Ọyọ.
Ọdun mejilelaaadọta ni Olayiwọla Adeyẹmi lo lori itẹ ko too papoda. Oun si lọba to pe lori oye ju lọ ninu itan awọn Alaafin to ti jẹ niluu Ọyọ.