Aarẹ ati igbakeji ẹlẹsin kan naa ko nitumọ, adari to maa ṣejọba rere ni ka yan – Ọbasa

Faith Adebọla, Eko

Olori awọn aṣofin ipinlẹ Eko, Ọnarebu Mudaṣiru Ajayi Ọbasa, ti rọ awọn ọmọ orileede yii lati ma ṣe fi ẹtẹ silẹ pa lapalapa lori ọrọ yiyan awọn adari tuntun ninu eto idibo to n bọ, o ni ipo ti Naijiria wa n beere fun yiyan olori ati awọn onṣejọba to maa mu igba ọtun ati ijọba rere wa.

Ọbasa sọrọ yii nibi akanṣe eto idanilẹkọọ lori ẹsin Islam ti wọn maa n ṣe lọdọọdun, eyi to waye ninu ọgba ileegbimọ aṣofin Eko, l’Alausa, Ikẹja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, to kọja yii.

Olori awọn aṣofin naa ṣalaye pe loootọ ni awuyewuye ti dide lori ọrọ ki aarẹ ati igbakeji ẹ jẹ ẹlẹsin kan naa, ododo si ni pe ọrọ ẹsin ati ọrọ oṣelu wọnu ara wọn, ṣugbọn ohun to tọna ju, to si yẹ kawọn eeyan fun lafiyesi ju, ni yiyan ẹni to ni amuyẹ ati iriri to lati tukọ orileede lọ sebute ogo.

“Lawọn orileede agbaye yika aye, ẹri ti fihan pe ki i ṣe ẹsin tẹnikan n ṣe lo maa pinnu boya tọhun yoo ṣejọba daadaa tabi bẹẹ kọ, tori ẹsin Islam ati ti Onigbagbọ ko rẹsẹ walẹ ni orileede bii India, Singapore, China, sibẹ iṣejọba wọn tuba tuṣẹ ju ti awọn orileede ẹlẹsin to yi wọn ka lọ.

“Ni ilẹ Afrika wa paapaa, kawọn ẹsin meji wọnyi too de, to jẹ ẹsin abalaye lawọn adari wa n ṣe, sibẹ wọn ṣejọba rere to ba ilana ijọba demokiresi mu daadaa. Iyẹn lo ṣe n yaayan lẹnu pẹlu bi a ṣe fẹẹ fi ẹsin pinnu oṣelu lasiko yii?”

Ọbasa parọwa sawọn olori ẹsin mejeeji lati ma ṣe lo agbara wọn lori ohun to maa fa iyapa, ija ati ipinya, kaka bẹẹ, niṣe ni ki wọn tubọ fi ọrọ Ọlọrun bọ awọn eeyan ki wọn le ṣe ipinnu to dara, to maa mu ilọsiwaju wa fun Naijiria, to si maa fi kun alaafia ati igbaye-gbadun wọn.

Bakan naa ni awọn agba aafaa atawọn olukọ ẹsin Islam mi-in to sọrọ nibi ayẹyẹ naa kin Ọbasa lẹyin. Lara wọn ni gbajugbaja Imaamu ilu Ọfa, nipinlẹ Kwara, Sheik Muyideen Salman Husayn, Adajọ kootu ko-tẹ-mi-lọrun Sharia kan, Sheikh Ishaq Mustapha Zuglool Sunnusi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn sọrọsọrọ naa pe fun iṣọkan Naijiria, wọn si gbadura ki eto idibo ọdun to n bọ lọ nirọwọ irọsẹ, ko si mu ayipada rere ba orileede yii.

Leave a Reply