Ọrẹ ki i y’ọrẹ: Aarẹ Buhari ati Tinubu pade ni London

 Faith Adebọla

Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe Aarẹ orileede wa, Muhammadu Buhari, wa niluu London, nibi to ti n ri awọn dokita rẹ.

Bẹẹ lo han gedegbe lọsẹ to kọja nigba ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, sabẹwo si Olori ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti wọn sọ pe o rẹ oun naa diẹ, to si n gbatọju niluu oyinbo kan naa.

Iroyin to wa nibẹ ni bi Aarẹ ilẹ wa ati Aṣiwaju Tinubu tawọn mejeeji lọ fun itọju ara wọn ṣe pade, ti wọn si jọ ya fọto papọ. Fọto ọhun lo ti n fa awuyewuye loriṣiiriṣii lori ẹrọ ayelujara.

Lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ni fọto ọhun gba ori ẹrọ ayelujara kan. Ṣugbọn ko ti i ṣeni to le sọ, boya Buhari lo lọọ ki Tinubu ni o, abi Tinubu lo lọọ ṣabẹwo si Aarẹ Buhari.

Bẹ o ba gbagbe, loṣu to kọja ni Aarẹ Buahri loun fẹẹ lọ sibi ipade kan ti wọn ṣe lori eto ẹkọ lagbaaye, eyi to waye nilẹ Gẹẹsi. Bẹẹ ni Akọwe iroyin rẹ, Fẹmi Adeṣina, sọ nigba naa pe bi baba yii ba kuro nibi ipade ọhun, yoo ya ri awọn dokita rẹ fun ayẹwo.

Ṣe lati ọjọ bii mẹta naa lawọn eeyan ti n gbe e kiri pe o rẹ gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu. Nibi tọrọ ọhun le de, awọn kan n sọ pe aṣaaju ẹgbẹ APC naa ti ku.

Afi bi fọto oun ati gomina Eko ṣe jade wurẹ lọsẹ to kọja yii, nibi ti ọkunrin na ti ṣabẹwo si ọga wọn yii, to si sọ pe koko lara ọta rẹ le, ati pe alaafia lo wa.

Eyi ni wọn n sọ lọwọ ti Aarẹ Buhari ati Tinubu tun fi ya fọto, ti wọn si gbe e sori ẹrọ ayelujara. Lawọn eeyan ba n sọ pe awọn ayọrunbọ meji pade ara wọn.

Leave a Reply