Lasiko ti gbogbo araalu n pariwo, to fi mọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa loke okun, pe ki wọn fopin si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ya sọtọ lati maa gbogun ti idigunjale ati iwa ọdaran gbogbo ti wọn n pe ni SARS, ọtọ ni ibi ti awọn gomina ilẹ Hausa sun, ti wọn dori kọ. Awọn gomina to wa lawọn ipinlẹ kaakiri ilẹ Hausa ti sọ pe awọn fara mọ SARS ni tawọn, wọn ni ko maa lọ bẹẹ, ijọba ko gbọdọ fagi le e.
Nile ijọba, niluu Abuja, lawọn gomina ilẹ Hausa ọhun kora wọn lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ohun ti wọn si lawọn n fẹ lọwọ ijọba Buhari ni pe ko da ajọ SARS pada, ko ma ṣe da awọn to n ṣewọde kiri pe awọn ko fẹ wọn mọ lohun rara.
Bi wọn ṣe pari ipade wọn pẹlu Aarẹ ni alaga awọn gomina Hausa yii Gomina Lalong, ba awọn oniroyin sọrọ, ohun to si sọ ni pe ipa nla ni awọn ẹṣọ ọhun n ko ti a ba n sọ nipa eto idaabobo awọn eeyan ati dukia lagbegbe awọn.
Lalong fi kun ọrọ ẹ pe ki i ṣe gbogbo awọn ẹṣọ to wa ninu SARS naa ni iwa wọn ko dara, ati pe awọn kan wa ninu wọn ti wọn wulo gidi, ti wọn si n ṣiṣẹ wọn bo ti yẹ.
Gomina yii waa kadii ọrọ ẹ nilẹ pẹlu alaye pe bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan lorile-ede yii fara mọ ki wọn fagi le awọn ẹṣọ ọhun, sibẹ, ohun ti ẹka agbofinro ọhun nilo ni atunto gidi, eyi ti yoo jẹ ki wọn le jawọ ninu iwa ibajẹ, ti wọn yoo si mu iṣẹ wọn bii iṣẹ.