Jide Alabi Bo tilẹ jẹ pe awọn ọdọ kan ti bẹ sita bayii niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, Eko ati Abuja bayii, lati fẹhonu han ta ko awọn ẹṣọ agbofinro SARS, sibẹ Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ijọba oun ko ni i fojuure wo ẹni tọwọ ba tẹ pe o fi iwọde ṣe janduku.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni Aarẹ sọrọ yii nibi ipade kan ti awọn lọgaa-lọgaa nidii iṣẹ ologun nigba ti wọn n ṣafihan ẹ nigba to n ba awọn ọga agba nidii iṣẹ ologun naa sọrọ lati ile ijọba, niluu Abuja. Aarẹ sọ pe ẹnikẹni to ba lo ọrọ iwọde yii fi da ilu ru, ijọba oun yoo ba iru ẹni bẹẹ wọ ọ daadaa.
O ni ijọba oun ṣi ni in lọkan lati maa daabo bo ẹtọ awọn eeyan orilẹ-ede yii, ati pe awọn eeyan paapaa naa ko gbọdo yọ ayọkayọ lati ṣi ẹtọ ti wọn ni yii lo, fun idi eyi, ki kaluku ṣe jẹẹjẹ, ko ni i saaye fun iwa idaluru kan bayii, ati pe gbogbo eeyan pata lo gbọdo bọwọ fun ofin.