Aarẹ Buhari yoo ka aba eto iṣuna ọdun 2023 lọjọ Ẹti

Monisọla Saka

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni Olori orilẹ-ede yii, Aarẹ Muhammadu Buhari, yoo gbe aba eto iṣuna ọdun to n bọ, iyẹn owo to din diẹ ni ogun tiriliọnu siwaju awọn ọmọ ileegbimo aṣoju-ṣofin atawọn sẹnetọ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ, ẹgbẹlẹgbẹ tiriliọnu owo Naira nijọba apapọ ti ṣeto lati na fun ọdun 2023. Ida mẹẹẹdogun o le diẹ ni owo yii jẹ si aba iṣuna ọdun 2022, aba iṣuna yii naa ni yoo jẹ akagbẹyin fun Aarẹ Buhari, gẹgẹ bi saa eto iṣejọba rẹ yoo ṣe wa sopin lọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023.

Funra Buhari lo kọ iwe to fi gbe ọrọ naa siwaju awọn aṣofin agba, Dokita Ahmad Ibrahim Lawan, to jẹ olori ileegbimọ aṣofin agba ati Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, ni wọn ka a si gbogbo ile leti.

Ninu lẹta yii ni Buhari ti ṣalaye pe, “Mo n fi akoko yii sọ fun gbogbo ile pe laago mẹwaa aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2022, ni mo maa ka aba eto iṣuna ọdun 2023 si eti apapọ ileegbimọ aṣofin mejeeji. Ki abẹnugan ile jọọ fi sọkan.”

Lẹyin ti wọn ka lẹta yii tan ni Lawan sọ fun gbogbo ile pe Aarẹ funra ẹ lo maa waa ka aba naa si ileegbimọ aṣofin kekere ati agba leti lẹẹkan naa.

Ninu ọrọ tiẹ, Gbajabiamila ni, ‘‘Igbesẹ ati erongba Aarẹ lati ka aba eto iṣuna lọjọ Jimọ ọsẹ yii waye latari ipade toun ati Minisita feto iṣuna, Zainab Ahmed, ṣe lọjọ Ẹti ọsẹ to lọ lọhun-un, lojuna ati palẹmọ gbogbo ohun ti wọn fẹẹ nawo le lori lọdun to n bọ.

O waa rọ awọn akẹgbẹ ẹ lati peju-pesẹ sibi ipade naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

 

Leave a Reply