Akin Olugbade, ogbontarigi oniṣowo nla to tun jẹ Aarẹ Ọnakakanfo ilu Owu, nipinlẹ Ogun ti ku o. Arun Koronafairọọsi ni wọn lo pa ọmọ Yorùbá yìí lẹni ọdún mẹrinlelọgọta.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, niṣẹlẹ buruku yii waye. Ibi kan ti wọn n pe ni Paelon COVID Centre, n’Ikẹja, l’Ekoo, ni wọn sọ pe o ku si.
Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Owu ni wọn pe Olóògbé yìí, bakan naa lo tun jẹ gbajumọ nla to lorukọ dáadáa kaakiri. Ohun kan ti wọn láwọn eeyan tún mọ ọn si dáadáa ni ifẹ nla to ni ṣi oriṣiiriṣii mọto lati máa lo, paapaa ẹya mọto kan ti wọn n pe ni Rolls Royce.
Lágbayé loni–in, ohun ti wọn tilẹ n sọ ni pe oun lo fẹẹ fẹran ọkọ náà ju lọ.
Amofin ni Bolu Akingbade, o sì gba oye dokita ninu imọ nípa òfin tó jẹ mọ idasilẹ ileeṣẹ nileewe gíga Cambridge University, loke okun.
ALAROYE gbọ pe oniṣowo nla ni Akin Olugbade ti a bá n sọ nípa òwò ile kikọ, rírà àti títà. Bẹẹ lo tun gbajumọ dáadáa laarin awọn kọngila to n ṣe àwọn owo mi–in to niye lori àti iṣẹ banki paapaa.
Ileewe kan to n jẹ Corona School, ati King’s College, niluu Eko, ati Yunifasiti ilu London lo ti kawe gboye nla.
Ọjọ kejìlá, oṣu kẹrin, ọdún 1956, ni wọn bi i sinu ẹbi Oloogbe Babatunde Akin-Olugbade, ẹni tí i ṣe Balogun ilu Owu, oniṣowo nla ni wọn pe baba naa nigba aye ẹ̀ paapaaa.