Faith Adebọla
Owe Yoruba to sọ pe oku ọlọmọ ki i sun gbagbe, ti ṣe ṣe mọ gbogbo ọmọ Naijiria lara bayii, pẹlu bi ọkan lara awọn olori orileede wa to ti ku ṣe dide nigba to ri gbogbo wahala ati ipọnju ta a n la kọja ni Naijiria, to si taari owo gọbọi si wa pe ka fi gbọ bukaata wa.
Ko kuku sẹni meji ta a n peri ju Ọgagun Sani Abacha lọ, olori orileede wa laye ologun, laipẹ yii lo fi owo ranṣẹ si Naijiria, owo kekere kọ o, owo tabua ni, miliọnu mẹtalelogun owo dọla to jẹ ti wọn ba ṣẹ ẹ sowo Naira, owo ti i dẹru boṣi gidi ni, orileede Amẹrika lo fowo naa ran si wa lọtẹ yii.
Eyi si kọ nigba akọkọ tọkunrin to nifẹẹ awọn eeyan rẹ daadaa yii yoo kọju si wa ṣe loore, afi bii ẹni pe o ti mọ ipọnju tawọn eeyan orileede yoo doju kọ lọjọ iwaju, bawọn obi ṣe n tọju ogun pamọ de ọmọ wọn lọjọ iwaju, bẹẹ ni Oloogbe Sanni ha owo Naijiria kaakiri awọn orileede agbaye kan, to n da a pada fun wa kọngbẹ-kọngbẹ bi lilo ba ti kan an.
Ta lo n jiyan pe ko ri bẹẹ? Lọdun 2000 to fowo sọwọ si wa kẹyin, miliọnu lọna ọọdunrun owo dọla ($311.7 million) o le mọkanla ati aabọ l’Amẹrika taari si Naijiria, wọn lara owo Abacha to tọju sọdọ awọn ni.
Ni 2018, orileede Switzerland la ti gba owo lọdun yẹn, miliọnu okoolelọọọdunrun ati meji ($322 million), wọn lowo t’Abacha ni ki wọn da pada fun wa niyẹn.
Lọdun 2014, orileede Leichtenstein, l’Abacha ran, miliọnu lọna okoolerugba ati meje owo dọla ($227 million) lo fi ran wọn si wa. Boya o ti ṣe saa diẹ to ti fowo ṣọwọ si wa gbẹyin lo jẹ kowo naa pọ to bẹẹ, tori oun mẹjọ ṣaaju asiko naa, ọdun 2006 lo ti fi miliọnu mẹrinlelogoji ($44.1) ṣọwọ kẹyin latorileede Switzerland, ati miliọnu ọtalenirinwo le ẹyọ kan to fi ran wọn lọdun 2005.
Awọn famili Abacha kan naa jẹwọ pe owo Abacha kan ha sawọn lọwọ, owo nla ni, ajọ EFCC lo tọpasẹ ẹ debẹ, awọn si fẹẹ ko o kalẹ, n ni wọn ba yọnda biliọnu kan ati igba kalẹ ($1.2b).
Ko tan sibẹ o, orileede meji l’Abacha fowo ran lọdun 2003 si Naijiria, awọn mejeeji lo si jiṣẹ, Jersey jiṣẹ ọgọjọ miliọnu dọla ($160 million), Switzerland naa jiṣẹ miliọnu mejidinlaaadọrun-un dọla ($88 million), yatọ si miliọnu mẹrinlelọgọta mi-in ti wọn kọkọ fi jiṣẹ fun wa lọdọdun 2000.
Nibi t’Abacha fẹran awọn ọmọ Naijiria de, gẹrẹ to ku loṣu Kẹfa, ọdun 1998, ọdun naa ni wọn ti bẹrẹ si i gba owo wa lọwọ awọn mọlẹbi ẹ, miliọnu ẹẹdẹgbẹrin aabọ dọla ($750 million) ni wọn kọkọ fi bẹrẹ lọdun naa, nigba ti Ajagunfẹyinti Abdulsalami Abubakar gbajọba.
Ẹnikan ti inu rẹ ko ni i dun si bi Abacha ṣe n fowo abu ṣe Abu lalejo yii ni Aarẹ wa, Muhammadu Buhari, tori tipẹtipẹ sẹyin ni Buhari ti sọ pe Abacha ko jiwo Naijiria o, bẹẹ ni ko jale rara, o kan palẹ awọn owo kan mọ kuro nilẹ lọna aitọ ni, bo tilẹ jẹ pe ọrọ ti Buhari sọ nigba naa bi ọpọ eeyan ninu, wọn adape ole lọmọ mi n fẹwọ, adape agbere ni ṣina.
Ṣa, niṣe ni ka maa dupẹ lọwọ Abacha, ka si tun maa dupẹ pataki lọwọ awọn orileede to fowo ran, ti wọn si fi jiṣẹ, ka parọwa sawọn orileede yooku ti owo baba wa lọdọ wọn, ki wọn ma jafara lati ba wa ko o, tori a ṣi nilo owo lati gbọ bukaata wa, ka waa bẹ ijọba wa ki wọn dakun nawo ti Dadi wa, abiyamọ tootọ ti ko gbagbe awọn ọmọ ẹ, n taari si wa yii, fun anfaani wa, nile loko.