Polongo ibo nile ẹsin ko o rẹwọn he – INEC

Faith Adebọla

Pẹlu bi ọjọ tawọn ẹgbẹ oṣelu atawọn oludije wọn yoo bẹrẹ eto ipolongo ibo ojutaye ṣe sun mọle,  awọn aṣa kan to ti maa n waye lasiko ipolongo naa tẹlẹ ti dohun eewọ bayii, ajọ INEC ti ṣekilọ pe aṣa ka polongo ibo ni mọṣalaaṣi, tabi ni ṣọọṣi, tabi ka gbe eegun ati igunnuko jade, atawọn aṣa to fara pẹ ẹ ko gbọdọ waye lọtẹ yii, tori ẹnikẹni ti wọn ba mu nidii iru nnkan bẹẹ yoo fẹwọn jura, yoo tun sanwo itanran.

Ikilọ yii jade lasiko ti Kọmiṣanna ajọ naa lori eto iroyin, ilukoro ati ilanilọyẹ nipa eto idibo, Festus Okoye, n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja, lọjọ Abamẹta, Satide, lori ipalẹmọ ati ilana tawọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ tẹle lasiko ipolongo ibo wọn.

Okoye ni omi tuntun ti ru lagbo oṣelu ilẹ wa, ẹja tuntun si ti wọ ọ pẹlu iwe ofin eto idibo tuntun ti Aarẹ Muhammadu Buhari buwọ lu loṣu Keji, ọdun yii, eyi ti ajọ INEC n lo lọwọlọwọ, kawọn oloṣelu yaa tẹti silẹ tori ilu ti ko s’ofin l’ẹṣẹ o si.

N lọkunrin naa ba bẹrẹ si i ka awọn apa kan jade ninu iwe ofin eto idibo, o ka abala kejilelaaadọrun-un jade, o ni abala yii ti sọ ọ deewọ fun oludije ati ẹgbẹ oṣelu wọn lati sọrọ alufaaṣa, tabi ki wọn ṣẹẹkẹeebu sira wọn lasiko ipolongo, ko gbọdọ si itabuku ẹni, ikanra, ipẹgan ati lilo awọn ede ailọwọ eyikeyii.

O ni isọri kẹta, ni abala ọhun ṣofin pe awọn ibi ti wọn ti fẹẹ polongo ibo ko gbọdọ jẹ ile ijọsin bii mọṣalaṣi, ṣọọṣi tabi ibi tawọn ẹlẹsin abalaye ti n ṣe ẹsin wọn, wọn o si gbọdọ ki ọrọ ẹgbẹ oṣelu kan bọnu iwaasu wọn, ko gbọdọ si aṣẹ tabi imọran kan lati dari awọn olujọsin sinu ẹgbẹ oṣelu kan tabi omi-in.

“Ko ṣeni to gbọdọ mu eegun jade lati fi fa ero wa sibi ipolongo ibo rẹ, bẹẹ ni ko gbọdọ si lilo oriṣa tabi awọn nnkan ibilẹ kan lati fi faju awọn eeyan mọra lọọ sibi ipolongo ibo, boya ṣaaju ọjọ ipolongo tabi lẹyin ẹ paapaa.

“Bakan naa, abala kẹfa iwe ofin eto idibo yii sọ pe ẹgbẹ oṣelu kan, oludije tabi ọmọ-oye, titi kan ijoye ẹgbẹ, ko gbọdọ lo awọn ẹṣọ alaabo ti wọn gbe nnkan ija oloro dani, ibaa jẹ ẹṣọ alaabo aladaani tabi tijọba, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ pe awọn ẹgbẹ ajijagbara tabi awọn ẹgbẹ alaabo ilu pe ki wọn le pese aabo fawọn nibi ipolongo tabi lasiko ti eto idibo n lọ lọwọ,” Okoye lo n ṣalaye ọrọ bẹẹ.

Ki lo maa ṣẹlẹ sawọn to ba rufin ọhun?

Ọkunrin naa sọ pe iwe ofin naa ti to ijiya tijọba maa fi jẹ awọn arufin lẹsẹẹsẹ sinu iwe naa. O ni: “Ẹgbẹ oṣelu, oludije tabi ọmọ-oye to ba ṣẹ lodi si abala kejidinlaaadọrun-un iwe ofin yii, o ti rufin, to ba jẹ oludije ni, yoo sanwo itanran ti ko ni i din ni miliọnu kan Naira, tabi ko ṣẹwọn oṣu mejila. Ṣugbọn to ba jẹ ẹgbẹ oṣelu lo jẹbi ẹsun yii, faini miliọnu meji Naira ni, iyẹn to ba jẹ igba akọkọ to dẹṣẹ niyẹn, ṣugbọn to ba jẹ igba keji, yoo maa fi miliọnu kan Naira le si iye to yẹ ko san.

“Ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ, to si jẹbi ṣiṣe agbodegba fawọn janduku lati gbe sẹyin oludije kan ki wọn si kọlu oludije mi-in, faini ẹẹdẹgbẹta naira tabi ẹwọn oṣu mẹta ni yoo fi jura, tabi mejeeji.”

INEC lo ṣalaye bẹẹ.

 

Leave a Reply