Nitori fidio, Baba to bi Alaaja le e kuro nile n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Itiju nla lo ba ọmọbinrin kan to jẹ akẹkọọ ileewe gbogboniṣe to wa nipinlẹ Ọyọ, pẹlu bi ọrẹkunrin rẹ ṣe gbe fidio ibi ti wọn ti ba ara wọn laṣepọ sori ẹrọ ayelujara, eyi to mu ki baba ọmọbinrin naa binu le e jade nile.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, oye akọkọ lọmọbinrin tọpọ awọn ẹgbẹ ẹ maa n pe l’Alaaja yii ṣẹṣẹ pari ninu imọ nipa ayẹwo ẹjẹ (Science Laboratory Technology) nileewe gbogbonise kan naa ti ọrẹkunrin ẹ ọhun n lọ, bo tilẹ jẹ pe ọmọlẹyin rẹ lọkunrin naa jẹ nileewe, nitori iyẹn ko ti i pari ẹkọ tiẹ.

Eto ifimọkunmọ iwe (Industrial Training) ọlọdun kan to yẹ ki Alaaja ṣe lẹyin ẹkọ naa lo n ṣe lọwọ nileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣayẹwo ẹjẹ n’Ibadan, to fi wa ọrẹkunrin ẹ ta a forukọ bo laṣiiri yii lọ sile, ti wọn ba ara wọn laṣepọ.

Gbogbo bi wọn ṣe n ṣe kinni ọhun lọkunrin naa ka silẹ pẹlu ẹrọ ibanisọrọ rẹ, ko si sẹni to mọ boya awọn mejeeji ni wọn jọ mọ nipa ẹ, nnkan to ṣaa han ninu fidio ọhun ni bi Alaaja ṣe jokoo le ololufẹ ẹ lori, to si fi ọwọ ara ẹ fi kinni ololufẹ ẹ sabẹ.

Fidio yii la gbọ pe ọmokunrin naa fi ranṣẹ sori ikanni ẹrọ ayelujara kan ti wọn n pe ni Teligram. Bi awọn ẹlẹgbẹ ẹ to fi i ranṣẹ si ṣe ri i ni kaluku wọn naa n fi i ranṣẹ sibomi-in. Bẹẹ ni fidio ibalopọ naa di ohun ti gbogbo aye n ri kaakiri nibi gbogbo.

Gbogbo ara ti Alaaja da ninu fidio yii ni baba ẹ paapaa foju ara ẹ wo. Irira itu ti ọmọdebinrin ti ko ju ẹni ogun ọdun lọ yii pa ninu fidio ta a wi yii lo mu baba naa le e jade nile pẹlu ibinu, ko ma ko iranu to n ṣe kiri igboro ran awọn aburo ẹ ninu ile.

Leave a Reply