Ijọba Dapọ Abiọdun tọwọ bọwe adehun pẹlu ileeṣẹ tuntun l’Ogun

Gbenga Amos

Bi gbogbo eto naa ba lọ bi wọn ṣe sọ, ko ni i pẹ tawọn ọdọ ti ko riṣẹ ṣe nipinlẹ Ogun yoo fi maa ribi ṣiṣẹ ounjẹ oojọ wọn, ti wọn yoo si maa rowo gbọ bukaata, latari bi ijọba ipinlẹ naa ṣe n wọnu adehun pẹlu awọn olokoowo aladaani lati da awọn ileeṣẹ nla nla silẹ nipinlẹ Ogun.

Iru adehun bẹẹ leyi to waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ yii, nigba ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ati ileeṣẹ nla kan, African Industries Group, tọwọ bọwe adehun lati da ileeṣẹ ti yoo maa rọ irin, ileeṣe ahurin-tunrin-rọ kan silẹ nipinlẹ naa laipẹ.

Alaga ileeṣẹ ọhun, Ọgbẹni Raj Gupta, eebo ọmọ ilẹ India, lo ṣoju ileeṣẹ rẹ nibi ipade kan to waye nileejọba ipinlẹ naa l’Oke-Mọsan, l’Abẹokuta, pẹlu gomina.

Gupta ni ileeṣẹ ti yoo maa ṣe ipese irin ati alumin, iyẹn aluminium naa yoo na wọn to ẹẹdẹgbẹta miliọnu owo dọla ($500 million) ki wọn too fidi ẹ mulẹ, ṣugbọn eto ti wa ni sẹpẹ lori eyi.

O ni, o kere tan, iye eeyan ti ileeṣẹ yii yoo fa jade kuro lara awọn alainiṣẹlọwọ, ti wọn yoo di oṣiṣẹ to n gbowo oṣu nipinlẹ Ogun yoo ju ẹgbẹrun marun-un lọ, yatọ sawọn ontaja atawọn ti yoo tun maa ṣe oriṣii awọn okoowo mi-in, ti wọn yoo si maa janfaani lara ileeṣẹ naa.

Oyinbo naa sọ lẹyin ipade wọn pe, inu oun dun si itẹsiwaju ti ijọba Abiọdun ti mu ba ipinlẹ Ogun lẹka okoowo ati ipese iṣẹ, o si tun dupẹ bijọba ṣe gbaruku ti wọn, ti wọn si pese awọn nnkan ti yoo mu ki iṣẹ wọn rọrun, ki wọn le tete bẹrẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ mẹta sẹyin nijọba ipinlẹ Ogun gbe iru igbesẹ to jọ eyi pẹlu ileeṣẹ mi-in loju ọna ati pese iṣẹ fawọn eeyan ipinlẹ naa.

Leave a Reply