Irọ ni o! A ko yọ ẹnikẹni ninu awọn to n dupo Alaafin- Baba Iyaji

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lati ọsẹ to kọja, titi di ba a ṣe n kọ iroyin yii, ko si iroyin to da awuyewuye silẹ ni ipinlẹ Ọyọ ju ọrọ eto lati fi ọba tuntun jẹ lode Ọyọ lọ.

Lati ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2023, ti Alaafin Ọyọ karundinlaaadọta (45), ti Ọba Lamidi Adeyẹmi ti waja lawọn afọbajẹ ti wa lori akitiyan lati fi ẹlomi-in jọba ilu iṣẹnbaye naa, ọmọ oye mọkandinlọgọfa (119) lo si ti fifẹ han lati gori apere baba nla wọn to ṣofo ọhun.

Ṣugbọn lọsẹ to kọja niroyin kan lu jade pe diẹ ninu awọn afọbajẹ Ọyọ, Agunpopo, Arole, Ọna Iṣokun Atingiṣi pẹlu Baba Iyaji, iyẹn Ọmọọba Mukaila Afọnja ti i ṣe olori awọn ọmọọba Ọyọ lọwọlọwọ, ṣepade pẹlu awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii, wọn si yọ orukọ mọkanlelọgọta danu ninu awọn ọmọ oye wọnyi, to fi jẹ pe ninu mejidinlọgọta yooku to kogo ja ni wọn yoo ti mu ọkan ṣoṣo tí yóò pada jọba ninu wọn.

Iroyin to da igboro ru gan-an niyi nitori pupọ ninu awọn idile to lẹtọọ si ipo Alaafin, to fi mọ awọn ti ko tilẹ ba idile ọba Ọyọ tan rara ni wọn fara ya lori igbesẹ ti wọn ni ijọba ati awọn afọbajẹ gbe yii.

Lara awọn araalu ti wọn fibinu sọrọ lori igbesẹ yii ni Ọgbẹni Bọsun Amọo ati Taiwo Ademọla. Amọo sọ pe “Wọn ti n fi oṣelu bọ ọrọ oye Alaafin, idi ti wọn ṣe n fi i falẹ gan-an niyẹn. Loju temi, wọn ti mọ idile ti ọba kan, ko si yẹ ki wọn fi kinni yii falẹ to bayii rara.

Ni ti Ọgbẹni Ademọla, o ni nibi ti wọn n ba kinni yii lọ yii, afaimọ lọrọ yii ko ni i pada di ohun ti wọn n gbera wọn lọ sile-ẹjọ si nigba ti wọn ba pada mu ẹni ti wọn fẹẹ fi jọba tan”.

Lara awọn ọmọọba Ọyọ to ta ko iru igbesẹ bẹẹ l’Ọmọọba Afọlabi Ademọla Adeṣina, ẹni to la ọrọ mọlẹ pe o ti pẹ diẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ti n gbe igbesẹ lati ri i daju pe ọkan ninu awọn to n dupo Alaafin lati idile Agunloye ni wọn yoo papa joye nla naa.

O ni ṣaaju nijọba ipinlẹ Ọyọ, nipasẹ ileeṣẹ to n ri si akoso ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ, ti ran olootu ijọba ibilẹ Atiba si Baba Iyaji lati pa a laṣẹ pe idile Agunloye ni wọn gbọdọ ti fa ẹni to maa jọba kalẹ.

Ọmọọba Adeṣina waa rọ ijọba lati fun igbimọ awọn afọbajẹ Ọyọ laaye lati ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bi ofin ṣe gbe agbara naa wọ wọn lati yan ẹni to ba tọ sori apere, ṣugbọn o, ki wọn ni suuru ki ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ oye yii pari na ki wọn too gbe igbesẹ kankan lori atifi ọba tuntun jẹ.

ALAROYE pe Biṣọọbu-Agba Ayọ Ladigbolu, ti oun naa jẹ ọkan ninu awọn to n dupo ọba naa lati gbọ tẹnu ẹ lori ọrọ to wa nilẹ yii, baba to jẹ ọkan ninu awọn ọmọ oye to n dupo Alaafin lati idile Agunloye yii woye pe ijọba ipinlẹ Ọyọ, Alaafin Ọyọ ati suuru lo ṣee yanju ọrọ to wa nilẹ yii.

Ladigbolu, ẹni to jẹ ọkan ninu awọn to n dupo ọba lati igun Agunloye sọ pe loootọ, idile oun lofin ti ijọba n lo lọwọ bayii ti fẹẹ yan ọba tuntun, sibẹ, oun paapaa fara mọ ọn pe ki wọn maa fun awọn idile ti ko ti i jọba ri naa lanfaani lati maa gori itẹ Alaafin nitori ori apere baba gbogbo awọn jọ ni.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘Wọn ko ti i gbe orukọ awọn to pegede jade. Ṣugbọn idile tiwa gan-an ni ti Agunloye. Wọn o le yọ awa kuro nibẹ, nitori ofin to wa nilẹ ti ijọba n lo, ofin yẹn naa ni wọn ṣi fẹẹ lo bayii.

‘‘Ootọ ni pe ọmọ baba kan naa jọ ni gbogbo wa, nitori Alaafin Atiba lo ṣẹ gbogbo wa silẹ. Ṣugbọn nigba ti ofin ti waa wa lorii pe ta loye kan lero yii, ijọba ti sọ pe ofin yẹn lawọn yoo tẹle. Bi atunṣe yoo ba tiẹ wa, o di ọjọ mi-in.

‘‘Wọn ki i si i ṣe atunṣe oye jijẹ lai ṣe pe ọba n bẹ lori itẹ. Iyẹn ni ko ye ọpọlọpọ eeyan. Ti wọn yoo ba ṣatunṣe yẹn, ti emi yii gan-an si fara mọ pe o yẹ ka ṣe nigba to ba ya, wọn gbọdọ fara balẹ ni. Gudugudu kan ko si le yi ofin pada. Ariwo gee ko le yi ofin pada. Gbogbo awa ọmọọba gbọdọ tẹle ofin ni, nitori abẹ ofin ni gbogbo wa wa, ẹni kan ọ ga ju ofin lọ. Gomina to si sọ pe ofin to n bẹ nilẹ loun yoo lo, o ni ohun to ri.’’

Ṣugbọn olori idile Adelabu, ọkan ninu awọn arọmọdọmọ Alaafin Atiba to lẹtọọ sipo Alaafin Ọyọ, Alhaja Sidikatu Ejide Ọlọna, sọ pe ofin atijọ ni Biṣọọbu-agba Ladigbolu n tọka si yẹn, ijọba ipinlẹ Ọyọ funra rẹ lo si ṣofin tuntun ọhun to pa ofin atijọ to n sọ rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Idile Agunloye nikan ni wọn ba ṣepade, wọn o pe awọn idile yooku si i rara. Awọn ọmọọba mọkanlelọgọta ti iroyin sọ pe wọn wọgi le wọnyẹn, wọn o ṣepade kankan pẹlu wọn, yala ki wọn too wọgi le wọn tabi lẹyin ti wọn gbe igbesẹ yẹn tan.

“Bakan naa ni wọn ko fi iwe kankan ranṣẹ si wa lati fi igbesẹ ta a gbọ pe wọn gbe yii to wa leti. A kan deede ka a lori ẹrọ ayujara pe wọn wọgi le wa naa ni. Eyi jẹ ami iwa igberaga ti ijọba hu si awa ọmọọba.

Bii pe ijọba fi ṣẹkẹṣẹkẹ de Baba Iyaji lọwọ pe ko ba idile yẹn ṣepade ni. Baba Iyaji ni lati ṣepade yii nitori wọn ni bi aṣẹ yẹn ṣe wa latoke niyẹn. Lẹyin yẹn la gbọ pe awọn mejidinlọgọta (58) pere ni wọn mu ninu awọn ọmọ oye. Gbogbo awọn mejeejidinlọgọta wọnyi, idile Agunloye nikan ni wọn ti wa. Wọn wọgi le gbogbo awọn ọmọ Atiba yooku. Baba Iyaji ko si fi iwe kankan to fọwọ si ranṣẹ si wa. Ki ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ijọba ibilẹ Atiba ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ fun wa, ki wọn jẹ ka mọ ibi ti iroyin yii ti wa.

“Ijọba ko lẹtọọ lati ba awọn afọbajẹ da si eto ti wọn fi maa fa ọmọ to maa jọba kalẹ. Bawo ni wọn ṣe maa yọ awọn ọmọ oye ti idile yooku fa kalẹ kuro nigba to jẹ pe ipo baba nla wọn ti gbogbo wọn jọ lẹtọọ si ni wọn jọ n du”?

Iya ẹni ọdun mẹrinlelaaadọrun-un (94) yii tẹsiwaju pe “iya ni mo jẹ si gbogbo awọn ọmọ Atiba to n lakaka lati gori itẹ baba nla wọn. Nitori naa, itan ye mi daadaa, bẹẹ naa ni mo si mofin to rọ mọ ọrọ ọba jijẹ lode Ọyọ. Ati itan ati ofin lo yẹ ka maa lo, ka le maa pin ipo yii dọgbandọgba laarin awọn ọmọ Atiba to lẹtọọ sipo baba wọn.

“Ofin ọdun 1961 nijọba n tẹle lati fi Alaafin jẹ. Ofin atijọ leyi, nitori igbimọ ti ijọba gbe kalẹ, eyi ti Ladẹhinde dari, ti gbe ilana tuntun jade lọdun 1976 lati maa fi yan Alaafin Ọyọ. Ilana tuntun yii lo faaye silẹ lati maa fi ọmọ oye jọba pẹlu ilana to tọ, to si wa ni ibamu pẹlu ibẹru Ọlọrun, nitori gbogbo idile to lẹtọọ sipo Alaafin pata lofin tuntun yii ko sinu.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ tun gbe igbimọ oluwadii kan dide lọdun 1995 ti wọn pe ni Ọlọkọ Commission of Inquiry. Abajade iwadii igbimọ ti Ọlọkọ dari yii tun fidi ẹ mulẹ pe eto tuntun ti igbimọ Ladẹhinde gbe kalẹ lati maa fi yan Alaafin Ọyọ gan-an lo tọna ju lọ, oun lo yẹ kijọba maa lo.

“Bi awọn ọmọkunrin Atiba mọkọọkanla ti wọn lẹtọọ lati maa jẹ Alaafin ṣe to tẹle ara wọn niwọnyi Adelu Agunloye (akọbi), Agbọin Adelabu, Adeṣiyan, Adeyẹmi Alowolodu, Tẹla Agbojulogun, Adeṣetan, Tẹla Okitipapa, Adeṣọkan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

“Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe awọn meji pere, iyẹn idile Adelu Agunloye ati idile Adeyẹmi Alowolodu nikan ni wọn ti i jẹ Alaafin ninu mọkọọkanla latigba ti Alaafin Atiba ti tẹ Ọyọ tuntun ta a wa yii do.

“Eeyan mẹrin lo ti jọba ni idile Agunloye, orukọ wọn ni Adelu Agunloye funra rẹ, Lawani Agogoija, Ṣiyanbọla Ladigbolu ati Bello Gbadegẹṣin. Ni idile Adeyẹmi Alowolodu, mẹta ninu wọn lo ti jẹ Alaafin. Orukọ wọn ni Adeyẹmi Alowolodu Kin-in-ni, Adeniran Adeyẹmi Keji ati Lamidi Adeyẹmi Kẹta. Awọn igun mejeeji to ti jọba niyẹn ninu awọn ọmọ Atiba, awọn ọmọ yooku ko ti i jẹ, bẹẹ ni ko ti i si ọmọ wọn kankan to jọba’’.

O waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lati fun awọn idile Atiba ti ko ti i jọba ri lanfaani lati gori apere baba wọn.

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, boya leto lati yan Alaafin Ọyọ tuntun le lọ wọọrọwọ lai jẹ pe wọn yanju ẹ pẹlu ija. Ọwọ ofin lo si ṣee ṣe ki wọn fi ja ija naa, iyẹn bi ko ba la nnkan mi-in lọ.

Ṣugbọn Baba Iyaji, olori awọn ọmọọba ti wọn lo yọ orukọ awọn idile kan kuro ninu iwe idibo iye ọba sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ.

Ọmọọba Afọnja ṣalaye fakọroyin wa lori ẹrọ ibanisọrọ pe “Ipade ta a ṣe yẹn, a pe awọn agbaagba lati idile Agunloye lati waa fidi awọn ọmọ oye to ti ọdọ wọn wa mulẹ ni, boya a le ri ninu awọn to n duye lorukọ idile wọn, to jẹ pe ki i ṣe ọmọ idile Agunloye.

Ohun ta a fẹẹ ṣe ni lati mọ awọn ojulowo ọmọọba. Ori idile Agunloye la ti bẹrẹ eto yii, a ko ti i yọ ẹnikẹni kuro ninu awọn to n dupo Alaafin.

“Onikaluku wọn n ṣe tiwọn ni. Loootọ nipade waye, ṣugbọn a ko ti i yọ ẹnikankan”.

 

Leave a Reply