Agbalẹ ni Sunday ni papakọ ofurufu Eko, o tun n gbe egboogi oloro

Faith Adebọla

Ọwọ palaba ọkunrin kan ti wọn porukọ ẹ ni Sunday Ohiagu, ọmọ bibi ipinlẹ Anambra yii ti segi, iṣẹ agbalẹ ati imọtoto ayika ni wọn gba a fun ni papakọ ofurufu Muritala Muhammed to wa n’Ikẹja, l’Ekoo, iṣẹ naa si lawọn ọga rẹ ro pe o n ṣe to si n gbowo oṣu, ko sẹni to fura pe baba ẹni ọdun mejilelogoji (42) naa ti ya bara sidii iṣẹ arufin mi-in, o ti n ṣe okoowo egboogi oloro labẹnu, wọn lo ti dọga laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n huwa ọdaran ọhun, ki aṣiri rẹ too tu laarin ọsẹ to kọja yii, ti wọn si mu un.

Alukoro ajọ to n gbogun ti okoowo, ilo ati gbigbe egboogi oloro nilẹ wa, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sori ikanni Alaroye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ yii.

Babafẹmi ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja lọwọ awọn agbofinro tẹ Sunday, arinrin-ajo ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (34) kan to porukọ ẹ ni Obinna Jacob Osita lo taṣiiri ẹ, Osita fẹẹ wọ baaluu ero Airpeace ni papakọ ofurufu MMIA, Ikẹja, lọ siluu Dubai, lorileede United Arab Emirate (UAE), o gbe baagi mẹta dani, o fẹẹ gbe awọn baagi naa wọ baaluu, nigba ti wọn si bi i leere pe ki lo wa ninu ẹru ọwọ ẹ, o ni aṣọ, gaari, ede ati awọn nnkan tẹnu n jẹ loun n gbe lọ fawọn mọlẹbi oun ni Dubai.

Ṣugbọn gbogbo bi wọn ṣe n gbe awọn baagi naa kọja lori ẹrọ ti wọn fi n ṣayẹwo ẹru, bẹẹ lẹrọ naa n han goorogo, eyi to fi han pe Osita lẹbọ lẹru, n ni wọn ba bẹrẹ si i tu awọn ẹru naa, wọn ba gaari loootọ, wọn si ri apo ede to di kudukudu sibẹ, ṣugbọn laarin gaari ati ede, egboogi oloro lo fi ha aarin wọn, ayẹwo si ti fihan pe Cannabis sativa, ti wọn n pe ni igbo, lo wa nibẹ.

Awọn ẹru ofin naa tẹwọn to kilogiraamu mẹrin o le diẹ (4.25kg), nigba ti wọn si ṣewadii, Osita, ọmọ bibi ipinlẹ Imo,  jẹwọ pe oun kọ loun lẹru o, oṣiṣẹ ẹẹpọọtu naa, Obinna, lo ni in, o lo kan fi oun boju ni, lakara ba tu sepo.

Wọn ti mu awọn mejeeji, wọn si ti wa lahaamọ awọn ẹṣọ NDLEA ti wọn n ba iṣẹ iwadii niṣo. Wọn lawọn mejeeji ti jẹwọ bi ọrọ ṣe jẹ, Osita si ṣalaye pe awọn to n ba afurasi ọdaran naa ṣiṣẹ ṣi pọ, ti wọn n ba a gbe egboogi oloro lọ siluu oyinbo.

Babafẹmi ni awọn otẹlẹmuyẹ ti n ba iṣẹ lọ lati tuṣu desalẹ ikoko, ati lati mu gbogbo awọn ẹmẹwa agbalẹ to n gbegboogi oloro yii.

Leave a Reply