Abubakar wọ banki bii ẹni to fẹẹ fowo pamọ, lo ba ji ọkada nibẹ l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Abubakar Salleh ree, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni. Niṣe lo wọ banki kan ni Panṣẹkẹ, l’Abẹokuta, bii ẹni to fẹẹ fowo pamọ, afi bo ṣe lọọ ji ọkada tẹnikan paaki kalẹ sinu ọgba naa, iyẹn lọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii.

Ohun ti ikọ Amọtẹkun to pada ri Abubakar mu sọ ni pe o ti ri ọkada naa ti nọmba ẹ jẹ  AYE 811 VN gbe sa lọ lai si idiwọ, ko too di pe ẹni to ni in jade sita ti ko ri alupupu rẹ mọ, to si figbe ta.

Nibi ti Abubakar ti n gun ọkada naa kaakiri ni awọn ti wọn ti n wa a ti da a duro ni Lafẹnwa, wọn mu un ṣinkun lọ sinu ọgba wọn, iyẹn awọn Amọtẹkun.

Wọn ti ni awọn yoo taari rẹ sawọn ọlọpaa fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Leave a Reply