Aburo iyawo ẹ ni Jonas ki mọlẹ, lo ba ṣe e yankanyankan ni Festac

Faith Adebọla, Eko

 

 

Jonas Nnubia ni wọn porukọ baale ile ẹni ọdun mẹrinlelogoji yii, akolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to n wadii ọrọ wo lẹnu ẹ lo wa bayii, ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii ni wọn mu un latari bi baba naa ṣe ki aburo iyawo ẹ ti ko ti pe ọdun mejidinlogun mọlẹ, o si fipa gba ibale ọmọ ọhun.

Adugbo First Avenue, L Close, niluu Festac, nipinlẹ Eko, ni wọn pe adirẹsi ibi tiṣẹlẹ ọhun ti waye, ibẹ ni wọn lọkunrin yii n gbe pẹlu iyawo ẹ, ataburo iyawo ẹ ta a forukọ bo laṣiiri.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti sọ pe ọpẹlọpẹ ẹgbẹ ajafẹtọọ awọn ọmọde kan, Child Protection Network, to gbọ nipa iṣẹlẹ buruku naa to fọrọ naa to awọn ọlọpaa teṣan Festac leti.

Ninu iwadii ti ẹgbẹ ajafẹtọọ naa atawọn ọlọpaa ṣe, ọmọbinrin yii jẹwọ pe ki i ṣe ẹẹkan lọkọ aunti oun ti fipa ba oun lo pọ, o ni ninu oṣu ki-in-ni, ọdun yii, lo ki oun mọlẹ nirọlẹ ọjọ kan ti aunti oun pẹ ko too tibi iṣẹ de, lo ba fipa ṣe kinni foun, ọjọ naa lo ni o gba ibale oun.

O lọkunrin naa bẹ oun nigba toun n ke, o si halẹ mọ oun pe oun maa foju oun ri mabo toun ba fi le jẹ ki aunti oun gbọ, o si tun ba oun sun lẹyin ọjọ naa.

Eyi lo mu ki wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe e lọjọ Abamẹta, Satide yii, ni wọn ba taari ẹ sawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ Panti, ni Yaba, lẹka ti wọn ti n mojuto iwa ọdaran abẹle atawọn nnkan to jẹ mọ bẹẹ, wọn si ti gbe ọmọbinrin naa lọ sọsibitu fun ayẹwo ati itọju iṣegun.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, lawọn o ni i jẹ ki ẹlẹṣẹ lọ lai jiyalori ọrọ yii, o lawọn maa tuṣu desalẹ ikoko

Leave a Reply