Adajọ ṣagbeyẹwo ẹri tawọn ọlọpaa fi ta ko Baba Ijẹsa ni kootu

Faith Adebọla, Eko

Furaidee, ọjọ Ẹti, opin ọsẹ yii, ni igbẹjọ tun tẹsiwaju lori ẹjọ ti gbajugbaja oṣere tiata ati adẹrin-in poṣonu ilẹ wa nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, n jẹ lọwọ ni kootu to n gbọ ẹsun akanṣe ati iwa iṣẹkuṣe, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.

Tẹ o ba gbagbe, latinu oṣu kẹrin, ọdun yii, ni wọn ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin naa lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ba ọmọdebinrin ọmọọdun mẹrinla kan laṣepọ, wọn lẹẹmeji ni Baba Ijẹṣa ti huwa ibajẹ ọhun pẹlu ọmọbinrin yii, akọkọ, nigba tọmọ naa wa lọmọọdun meje, ati nigba to di ọmọọdun mẹrinla, ko too di pe wọn ri i mu.

Lati oṣu keje si ni wọn ti foju afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ, ti igbẹjọ si ti n lọ lori ọrọ naa, bo tilẹ jẹ pe Adajọ Oluwatoyin Taiwo ti gba beeli Baba Ijẹṣa, pe ko maa ti ile waa jẹ ẹjọ rẹ, toun naa si n ṣe bẹẹ.

Lọjọ karun-un, oṣu kọkanla yii, ti Baba Ijẹṣa tun foju bale-ẹjọ naa, Amofin Kayọde Ọlabiran to jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro olujẹjọ sọ f’ALAROYE pe ẹri tawọn ọlọpaa jẹ ta ko olujẹjọ naa nile-ẹjọ tu palẹ, o lawọn agbẹjọro olujẹjọ beere ọrọ lọwọ ASP Kazeem nipa awọn ẹri ti wọn lawọn ri lasiko iwadii ti wọn ṣe nigba ti afurasi ọdaran naa fi wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba.

O ni igbẹjọ ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii, Adajọ Taiwo si ti sun igbẹjọ to n bọ si ọjọ kejila, oṣu kọkanla yii, kan naa.

O ni ọrọ ko ti i kan Baba Ijẹṣa lati ro arojare tirẹ, o ni lẹyin ti wọn ba pari gbigbọ alaye awọn olupẹjọ ni ọrọ yoo too kan Baba Ijẹṣa.

Lara ẹsun marun-un ti ijọba Eko fi kan Baba Ijẹṣa ni ifipa ba ọmọde lo pọ, fifọwọ kan ọmọ ọlọmọ lọna ti ko tọ, fifooro ẹmi ọmọde lati ba a laṣepọ, atawọn ẹsun meji mi-in, to tako iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko.

Leave a Reply