Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo, Onidaajọ Oyebiyi, ti paṣẹ pe ki baba agba kan ati ọmọ rẹ pẹlu aburo rẹ kan lọọ fi aṣọ penpe roko ọba fodidi ọdun kan tabi ki wọn sanwo itanran lori ẹsun ole jija ati igbimọ-pọ lati ba nnkan oninnkan jẹ.
Awọn olujẹjọ ọhun ni Yusuf Adeyẹmi, Sikiru Adeyẹmi to jẹ ọmọ rẹ ati Kazeem Adeyẹmi. Ninu ẹjọ naa, to ni nọmba HED/2c/2018, ni wọn ti fi ẹsun mẹwaa ọtọọtọ kan awọn olujẹjọ, ninu eyi ti mẹfa jẹ ẹsun iwa ọdaran.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ni ole jija, igbimọpọ lati huwa buburu, wiwọnu ilẹ onilẹ pẹlu ipa, titapa si aṣẹ ile-ẹjọ, biba nnkan oninnkan jẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gẹgẹ bi agbefọba lati ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun kọkanla (Zone 11) to wa niluu Oṣogbo ṣe sọ fun kootu, ọjọ kejilelogun, oṣu Keje, ọdun 2015, ni awọn olujẹjọ akọkọ, Yusuf Adeyẹmi, lọ si ori ilẹ kan to wa ni Aigbe/Arikese, ni Okinni, eleyii ti ile-ẹjọ ti sọ pe wọn ko gbọdọ de mọ, o si ka koko atawọn ere-oko mi-in.
Nigba ti awọn to ni ilẹ naa, Alhaji Saka Busari Ọlawale atawọn mọlẹbi rẹ, Akinyọde Oluyẹyin, pe e nija, ṣe lo ranṣẹ si ọmọ rẹ, Sikiru Adeyẹmi ati aburo rẹ, Kazeem Adeyẹmi pẹlu awọn kan ti wọn ti sa lọ bayii, ti wọn si doju ija kọ awọn ti wọn n ṣiṣẹ nibẹ.
Laarin ọdun marun-un ti wọn fi ṣe ẹjọ naa, agbefọba pe ẹlẹrii marun-un; Alhaji Saka Busari Ọlawale, Ẹnjinia Akeem Ọlawale, Inspẹkitọ Ogunlẹyẹ Thomas, Kasali Taiwo ati Sajẹnti Kọlawọle Ajiṣọla, nigba ti agbẹjọro olujẹjọ pe ẹlẹri mẹta, wọn si ko ẹsibiiti mẹtadinlogun kalẹ.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Oyebiyi, sọ pe awọn olupẹjọ ti fidi rẹ mulẹ pe olujẹjọ akọkọ ji koko (cocoa seeds), ẹyìn (palm fruit), bẹẹ ni olujẹjọ keji ati ikẹta atawọn mi-in ti wọn ti sa lọ bayii ji pọnnpọn, sọbiri ati jiga ti awọn oṣiṣẹ n lo.
Bakan naa lo ni wọn jẹbi igbimọpọ lati ba nnkan oni nnkan jẹ, wiwọnu ilẹ onilẹ ati titapa si aṣẹ ile-ẹjọ. Amọ sa, agbẹjọro wọn, Adewale Afọlabi rọ ile-ẹjọ lati fun wọn lanfaani owo itanran dipo ki wọn ran wọn sẹwọn.
Lẹyin naa ni adajọ paṣẹ pe ki awọn olujẹjọ mẹtẹẹta lọọ fi ẹwọn jura fodidi ọdun kan lori ẹsun wiwọnu ilẹ onilẹ, biba nnkan oninnkan jẹ, ati titapa si aṣẹ ile-ẹjọ, bẹẹ lo kilọ fun wọn lati ma ṣe de ori ilẹ naa mọ.