Adajọ ju Dauda ati Ibrahim to ji maaluu gbe sẹwọn ọdun marun l’Odigbo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Odigbo, ti ni kawọn Fulani darandaran meji, Abdulahi Ibrahim ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati Dauda Muhammed ọmọ ọdun mejilelogun fẹwọn ọdun marun-un marun-un jura lori ẹsun jiji maaluu onimaaluu gbe.
Ni ibamu pẹlu ẹsun ti wọn fi kan wọn ati ẹnikẹta wọn ti wọn porukọ rẹ ni Tajudeen Adiamot lasiko igbẹjọ, wọn ni ọganjọ oru ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn gbimọ pọ ji maaluu mẹta lagbegbe ọja Sabo, l’Odigbo.
Awọn maaluu ọhun ti apapọ owo rẹ to bii ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun-un Naira (#900,000) ni wọn lo jẹ ti ẹnikan ti wọn n pe ni Abubakar Muhammed.
Agbefọba, Usifo James, ni ẹsun mẹtẹẹta tí wọn fi kan awọn olujẹjọ naa ta ko abala ofin, okoolelẹẹẹdẹgbẹta din mẹrin (516), irinwo din mẹwaa (390) ati okoolenirinwo le meje) (427) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti Ọdun 2006.
Ni kete ti wọn ti ka ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ ọhun si wọn leti ni Abdulahi ati Dauda ti gba pe awọn jẹbi, eyi lo si mu ki Adajọ kootu naa, Onidaajọ D. O. Ogunfuyi, pinnu lati gbe idajọ rẹ kalẹ loju-ẹsẹ.
Adajọ ni ki awọn mejeeji lọọ fẹwọn ọdun mẹta mẹta jura lori ẹsun akọkọ, ati ẹwọn ọdun meji meji fun jijẹbi ẹsun keji.

Onidaajọ Ogunfuyi ni oun gba ki wọn gba beeli Tajudeen to jẹ ẹni kẹta wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira niwọn igba to ti loun ko jẹbi eyikeyii ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun ta a wa yii, ni wọn ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply