Ẹgbẹ awọn olukọ Fasiti fi ọsẹ mejila kun iyanṣẹlodi ti wọn n ba lọ.

Monisọla Saka
Ẹgbẹ awọn olukọni fasiti kaakiri orilẹ-ede yii, ASUU, ti tẹsiwaju ninu iyanṣẹlodi ti wọn ti gun le lati bii oṣu diẹ sẹyin, oṣu mẹta gbako ni wọn tun fi kun un bayii.
Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke, buwọ lu ni wọn ti ni awọn ṣe eyi lati le fun ijọba ni akoko, ki wọn le raaye yanju gbogbo ọrọ to wa nilẹ ọhun.
O tun jẹ ko di mimọ pe itẹsiwaju iyanṣẹlodi awọn ti bẹrẹ lati aago mejila oru kọja iṣẹju kan ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2022.

ASUU ni awọn ṣe ipinnu ọhun lẹyin ipade igbimọ apapọ ẹgbẹ ọhun, eyi to bẹrẹ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ni Comrade Festus Iyayi National Secretariat, Fasiti ilu Abuja.
Ninu atẹjade ọhun ni wọn ti ni, ‘‘Lẹyin ọpọlọpọ iforikori, ta a si ri aibikita ijọba lati ṣe ojuṣe rẹ, ati lati tete wa ojutuu si iwe ti ajọ ASUU kọ ti wọn fi fẹdun ọkan wọn han si ijọba apapọ lọdun 2020, lo mu ka fi ọsẹ mẹjọ kun iyanṣẹlodi ọhun lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta,
ọdun 2022. Igbimọ alaṣẹ ASUU ti fẹnu ko pe awọn yoo tun ṣafikun iyanṣẹlodi fun odidi ọsẹ mejila mi-in lati fun ijọba ni akoko si i, ki wọn le raaye yanju awọn ọrọ to wa nilẹ”.

Ninu atẹjade ti wọn pe akọle rẹ ni, “Ibi ti ọrọ iyanṣẹlodi ASUU de duro” ni wọn ti ni, “Awọn igbimọ alaṣẹ ASUU ti ṣepade pajawiri lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2022, l’Abuja. Ohun ti ipade ọhun da le lori ni lati ṣagbeyẹwo ibi tọrọ de duro latigba ti ẹgbẹ ọhun ti kede iyanṣẹlodi ọlọsẹ mẹjọ kun eyi ti wọn n ba
bọ lati ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2022. Iyanṣẹlodi ọhun waye latari iha ko-kan-mi tijọba kọ si
lẹta ti awọn ẹgbẹ ọhun fọwọ si ninu oṣu Kejila, ọdun 2020, lasiko ti wọn n dunaadura lori adehun ti ijọba apapọ ṣe fun wọn lọdun 2019”.
Wọn fi kun un pe, igbimọ ẹlẹni mẹta ti Aarẹ
Muhammadu Buhari gbe dide lọjọ kin-in-ni, oṣu Keji, ọdun 2022, lati yanju awọn rogbodiyan to ti n ja ran-in ran-in nilẹ laarin ASUU atijọba apapọ ko ti i pe ẹyọ ipade kan titi di oni yii.
O ni o jẹ ẹdun ọkan fun awọn igbimọ alaṣẹ yii pe, ipade kan ṣoṣo ti ASUU ṣe pẹlu igbimọ ti Nimi Briggs jẹ aṣaaju rẹ ko ri nnkan gidi kan ṣe lori ọrọ naa. Ẹgbẹ awọn olukọ yii ni ayafi ti wọn ba gbe igbesẹ lati yanju ọrọ ajọsọ to wa nilẹ lati oṣu Karun-un, ọdun 2021, lọrọ naa too le niyanju.
Wọn bu ẹnu atẹ lu iha ti ijọba kọ si iyanṣẹlodi naa pẹlu bi awọn akẹkọọ ko ṣe wa nileewe lati bii
oṣu mẹta, awọn oloṣelu wa n lọ soke sodo, ti wọn si
n kowo nla ra fọọmu lati fi dupo ninu eto idibo 2023 to n bọ lọna!
Awọn to wa nipo ti kẹyin si awọn fasiti ilẹ wa to n raago, to si n fẹ amojuto, ilẹ okeere ni wọn n paara lati dawọọ idunnu ayẹyẹ ikẹkọọ-jade awọn ọmọ wọn ti wọn kawe lawọn fasiti ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin nilẹ okeere
Lara awọn nnkan ti ASUU n beere lọwọ ijọba ni, ipese owo ironilagbara fasiti, titun adehun aarin ijọba apapọ ati ASUU to waye lọdun 2009 ṣe, ipese ajẹmọnu awọn olukọ fasiti ati ṣiṣe atunṣe si UTAS, iyẹn ikanni ti wọn n gba sanwo oṣu ati ajẹmọnu awọn olukọ fasiti.

Leave a Reply