Ọrẹoluwa Adedeji
Ọrẹ ki i ya ọrẹ, akobani ki i ya ara wọn, eyi lo gbe awọn ọrẹ meji kan, Hassan Abdullahi, ẹni ọgbọn ọdun, ati Yau Mohammed, ẹni ọdun mejilelogun, de ile-ẹjọ, nibi ti wọn ti n ṣalaye ohun ti wọn mọ nipa kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ti wọn ji gbe, ti wọn si lọọ ta a ni gbanjo.
Ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Jos, ni wọn wọ wọn lọ lori pe awọn mejeeji gbimọ-pọ, wọn lọọ ji kẹkẹ onikẹkẹ gbe, ti wọn si ta a ni owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira (670, 000.00).
Gẹgẹ bi ileesẹ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ṣe ṣalaye. Jẹẹjẹ ni ẹni to ni kẹkẹ yii, Adams Shuaibu, paaki rẹ silẹ, ti Abdullahi atọrẹ ẹ si lọ sibẹ, ti wọn ji i gbe.
Lẹyin ti wọn gbe e ni wọn lọọ lu kẹkẹ naa ta ni gbanjo. Ṣugbọn ọwọ ọlọpaa pada tẹ wọn, bẹẹ ni wọn si ri kẹkẹ ti wọn ji gbe ọhun gba lọwọ wọn. Wọn jẹwọ lasiko tawọn agbofinro n fọrọ wa wọn lẹnu wo pe loootọ lawọn lọọ ji kẹkẹ naa nibi ti ẹni to ni in paaki rẹ si, ti awọn si lọọ ta a.
Ẹni to ni ọkada yii, Adams Shuaibu, lo lọọ fọrọ naa to wọn leti lagọọ ọlọpaa Laranto, gẹgẹ bi Agbefọba, Laraban Ahmed, ṣe sọ. O ni awọn eeyan naa jẹwọ pe loootọ ni awọn ji ọkada yii, awọn si ti gba a pada lọwọ wọ.
Agbefọba ni iwa ti awọn ọrẹ meji ọhun hu lodi si ọkan ninu awọn ofin to de iwa idigunjale nipinlẹ naa.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ kootu naa, Thomas Ajitise, sọ pe bi ẹlẹjọ ba mọ ẹjọ rẹ lẹbi, ko ni i pẹ lori ikunlẹ lọrọ awọn ọrẹ meji yii pẹlu bi wọn ṣe jẹwọ pe loootọ ni awọn ṣẹ ẹṣẹ naa, ti wọn si bẹbẹ pe ki adajọ ṣiju aanu wọ awọn pẹlu ipinnu pe awọn ko ni i ṣe bẹẹ mọ. Eyio lo mu ki adajọ ran awọn ọrẹ meji yii lẹwọn ọdun meji meji.
Ṣugbọn o fi aaye faini ẹgbẹrun lọna aadọta Naira silẹ fun wọn gẹge bii owo itanran.