Adajọ ni ki ileeṣẹ ọlọpaa san miliọnu marun-un naira fun obinrin ti wọn fiya jẹ niluu Iwo lasiko igbele Korona

Florence Babaṣọla

 

Ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa ati ọga-agba patapata wọn san miliọnu marun un naira gẹgẹ bii owo gba-ma-binu fun ọmọbinrin kan ti wọn fiya jẹ lọna aitọ

A oo ranti pe loṣu kẹrin, ọdun 2020,ni awọn ọlọpaa kan na obinrin naa, Tọla Azeez, lọja Odo-Ori, niluu Iwo, nigba to fẹẹ lọọ ra oogun fun araale rẹ kan ti ara rẹ ko ya.

Ẹnikan to dọgbọn ka fọnran fidio iṣẹlẹ naa lo ju u sori ẹrọ ayelujaja, to si di eyi ti gbogbo awọn araalu n lu ẹnu atẹ lu. Ohun ti awọn ọlọpaa naa n sọ ni pe ko yẹ kobinrin naa jade ninu ile rara nitori ofin igbele Korona wa lode nigba naa.

Lẹyin ọjọ diẹ ni aṣiri awọn ọlọpaa naa tu, ti wọn si pe orukọ wọn ni Inspẹkitọ Ikuẹsan Taiwo ati Kọpurs Abass Ibrahim.

Lati fi ẹhonu han lori iṣẹlẹ yii, ajọ kan to n ja fun ẹtọ araalu nipasẹ agbẹjọro kan, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, fori le ile-ẹjọ lorukọ obinrin naa.

Lasiko atotonu wọn ni kootu, agbẹjọro fun ileeṣẹ ọlọpaa, F. B. Osei sọ pe oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni Taiwo ati Ibrahim, ko si yẹ ko jẹ ọga agba ọlọpaa tabi ileeṣẹ naa ni yoo jiya ẹṣẹ awọn mejeeji.

Ṣugbọn Ọlajẹngbesi sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ, o ni ẹnu iṣẹ ọlọpaa lawọn eeyan naa wa ti wọn fi huwa ti wọn hu.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori atotonu awọn agbẹjọro mejeeji, Onidaajọ Ayọ Emmanuel sọ pe olupẹjọ ni ẹtọ lati pe ẹjọ naa. O ni iwa ti awọn ọlọpaa hu jẹ titẹ ẹtọ olupẹjọ loju mọlẹ, ileeṣẹ ọlọpaa si gbọdọ ṣetan lati ru ẹru ẹbi ẹṣẹ wọn.

Nitori naa, adajọ paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa san miliọnu marun naira fun olupẹjọ.

 

Leave a Reply