Adajọ ni ki wọn lọọ yẹgi fawọn obinrin mẹta ti wọn jẹbi ẹsun ijinigbe

Faith Adebọla

 Boya owe awọn agba ti wọn ni ọdẹ ki i pa ọdẹ jaye, ko si yẹ ki abiyamọ maa da abiyamọ ẹlẹgbẹ rẹ loro lori ọrọ ọmọ rẹ lo mu ki inu bi Onidaajọ Gabriel Ette ti ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ silu Uyo, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Akwa-Ibom, lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹsun iwa ijinigbe, jiji awọn ọmọ keekeekee, tita awọn ọmọde soko ẹru, atawọn iwa ko-tọ mi-in ti wọn fi kan awọn abilekọ mẹta kan nile-ẹjọ naa. Adajọ yii ni  oju gba oun ti fawọn ọbayejẹ wọnyi, o si ya oun lẹnu pe obinrin ẹlẹgbẹ wọn, abiyamọ bii tiwọn, ni wọn n huwa aidaa bii eleyii si, lo ba paṣẹ pe iru awọn eleyii o tun gbọdọ wa loke eepẹ laarin awọn eeyan gidi, o ni ki wọn lọọ sokun mọ wọn lọrun, ki wọn si so wọn rọ diro-diro titi ẹmi yoo fi bọ lara wọn ni.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa yii, ni idajọ naa waye ta ko awọn obinrin ọdaran mẹta kan, Enobong Nsikak Sunday, ẹni ọdun mejidinlogoji (38) ti wọn loun gan-an lolori ikọ ajinigbe naa, Gertrude Thompson Akpan, ẹni ọdun mejidinlaaadọta (48), ati ẹni kẹta to dagba ju laarin wọn, Mary Okon James, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta (49).

Wọn lawọn obinrin wọnyi jẹbi ẹsun igbimọ-pọ lati huwa abeṣe, ijinigbe, ati fimọde ṣowo ẹru, eyi to lodi, to si ni ijiya to gbopọn labẹ isọri ki-in-ni iwe ofin aabo abẹle ati ifiyajẹni ti ipinlẹ Akwa-Ibom (Akwa Ibom State Internal Security and Enforcement Law) tọdun 2009.

Ọga awọn ajinigbe yii, Enobong Sunday jẹwọ lasiko ti igbẹjọ n lọ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, o ni abiyamọ loun naa o, ọmọ meji loun ti bi, ilu Atiamkpat, nijọba ibilẹ Nsit Ubium, loun si ti wa. Oo ni iṣẹ ijinigbe toun ṣe kẹyin tọwọ palaba awọn fi segi yii, ọmọdebinrin ọmọọdun meji kan lawọn ji gbe. O ni ibi isọji aṣemọju kan to waye ni ṣọọṣi ti wọn forukọ bo laṣiiri loun ti pade ọmọdebinrin naa, oun si ri i pe awọ iṣẹ ati iya wa lara ẹ, loun ba dọgbọn tẹle oun ati iya rẹ bi wọn ṣe n kuro nibi isọji nidaaji ọjọ keji lọ sile wọn ni adugbo Ifa Atai, o loun kọkọ fẹtan mu ọmọbinrin ọhun pe oun fẹẹ mu un lọ sọsibitu fun itọju, igba to tun ya, oun fun iya ọmọ naa lowo, ẹgbẹrun marun-un Naira (N5,000) pe ko fi ra nnkan jijẹ foun atawọn ọmọ ẹ nitosi ọja Transformer Junction, to wa lọna Abak, ṣugbọn mama naa ko gbowo ọhun lọwọ oun. Nigba toun ṣaa ri i pe ọgbọn toun ta naa ko jẹ, oun fibẹ silẹ. Ọjọ keji loun ṣẹṣẹ waa dari saduugbo naa, toun si ji ọmọbinrin naa gbe sa lọ.

Ni ti ọdaran keji, iyẹn Getrude Thomspson Akpan, o ni owo loun n fi awọn ọmọ tawọn ba ji gbe pa ni toun, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000) loun n ta ọmọ kan, ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000) loun maa n fun ẹni to ba mu ọmọ naa wa, toun yoo si da ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (N300,000) yooku sapo ni toun.

O leyii to bu awọn lọwọ yii, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2018, lawọn ji ọmọdebinrin to ku oṣu mẹrin ko pe ọmọọdun mẹta kan gbe, irọ tawọn pa funya ọmọ ọhun ni pe iyawo gomina ana ipinlẹ Akwa Ibom, Dokita Martha Udom Emmanuel, n ṣeto ironilagbara fawọn otoṣi, awọn si fẹẹ ba a mu ọmọ rẹ lọ sibẹ ki wọn le foun naa lẹbun to jọju, ki wọn si ṣeranwọ fun un, lawọn ba ji ọmọ ọhun gbe.

Ni ti ọdaran kẹta, Mary Okon James, o ni ẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000) ti wọn fun oun lori ọmọ toun ji gbe wa fun wọn lo wọ oun loju toun fi di ọkan lara awọn ajinigbe naa.

Onidaajọ Ette ni awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ oun, ati ijẹwọ tawọn afurasi wọnyi fẹnu ara wọn ṣe fihan pe ogbologboo apamọlẹkun jaye to ti ba iwa laabi ati ijinigbe mulẹ bii ẹgbẹ iṣu ni wọn. O lawọn obinrin naa ya ọdaju gidi, wọn si loro ninu pẹlu.

O bi wọn leere pe, “bawo lo ṣe n ri lara yin nigba tẹ ẹ ba fa ọmọọlọmọ lọwọ, tẹ ẹ si n lọọ ta wọn danu fun ere ijẹkujẹ, tẹ ẹ n fowo ẹmi awọn ọmọọlọmọ ati oogun oju abiyamọ bii tiyin ṣara rindin? Elewu eeyan lẹ jẹ lawujọ, iru yin yii o si gbọdọ gbilẹ rara, tori ọkan yin ti yigbi sidii iwa abeṣe tẹ ẹ gbe gunwọ yii. Pẹlu bo ṣe jẹ iwa ọdaran lẹ mu lọkun-un-kundun yii, ẹ ni lati gba ere iwa yin lẹkun-un rẹrẹ ni. Ẹ ti ji oorun silẹ, ẹyin naa o si ni i foju ba ooru debi tẹ ẹ maa waa lalaa. Ile-ẹjọ yii da yin lẹbi iwa ijinigbe ati ṣiṣe ọmọde yankan-yankan. Mo paṣẹ idajọ iku lori ẹyin mẹtẹẹta, ki wọn lọọ yẹgi fun yin. Ori okun ni ki wọn so yin rọ si titi tẹ ẹ fi maa ku fin-in fin-in. Ki Ọlọrun ṣaanu fun ọkan yin.”

Niṣe lawọn obinrin naa bu sẹkun gbaragada, amọ aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ, okete wọn ti degba alatẹ ko too maa keboosi.

Leave a Reply