Adajọ ni ki wọn lọọ yẹgi fun awọn to digunjale niluu Ọffa lọjọsi

Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ giga kan to wa nipinlẹ Kwara, eyi ti Onidaajọ Haleema Salman, n dari, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ so awọn ọdaran marun-un kan rọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn lọwọ ninu idigunle ati ipaniyan to waye lọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun 2018.

Awọn ọdaran naa ni wọn ko wa siwaju ile-ẹjọ giga naa ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, pẹlu ẹsun oniga marun-un to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi, idigunjale, ṣiṣe iku pa alaiṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Tẹ o ba gbagbe, awọn ọdaran mẹfa ni wọn ti n jẹjọ lati ọdun 2018 ti igbẹjọ ti bẹrẹ, ọlọpaa kan, Michael Adikwu, to ti ku, Ayọade Akinibọsun, Azeez Salaudeen, Niyi Ogundiran, Ibikunle Ogunlẹyẹ ati Adeọla Abraham, ni wọn fẹsun kan pe wọn lọọ digun ja banki kan lole niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, ti wọn si tun ṣekupa awọn eeyan rẹpẹtẹ.

Michael Adikwu, to jẹ olori awọn adigunjale ọhun ti ku, tawọn marun-un yooku si n tẹsiwaju ninu ijẹjọ wọn ki adajọ too sọ pe ki wọn lọọ yẹgi fun wọn bayii.

Awọn ọdaran naa ja fitafita lati ri i pe wọn bọ ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn pẹlu bi ọkan lara agbẹjọro wọn, Nathaniel Emeribe, to lewaju fun awọn agbẹjọro yooku ṣe sọ pe onibaara awọn ko jẹbi ẹsun naa, ati pe idajọ naa ba awọn lojiji, tawọn yoo si mori le ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun.

Ṣugbọn ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Haleema sọ pe, “Pẹlu gbogbo ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ yii, agbefọba ro ẹjọ rẹ yekeyeke, o si fi idi rẹ mulẹ ṣinṣin. Ki wọn lọọ yẹgi fun awọn ọdaran maraarun titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu wọn. Ki Ọlọrun foriji ẹmi wọn”.

Agbefọba, Barisita Rotimi Jacobs, fi idunnu rẹ lori idajọ naa, to si ni o tẹ oun lọrun.

Leave a Reply