Adajọ ni ki wọn lọọ yẹgi fun Joseph, ọjọ keji to bẹrẹ iṣẹ ọdẹ lo pa ọga rẹ ati ọmọ ẹ

Monisọla Saka

Gbogbo awọn ti wọn wa ni kootu ti igbẹjọ ọmọkunrin kan, Joseph Ogbu, to waye nile-ẹjọ giga to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn n kan saara si Onidaajọ Modupẹ Nicole-Clay, pe idajọ to tọ, to si tọna, ni obinrin naa da pẹlu bo ṣe ni ki wọn lọọ yẹgi fun ọmọkunrin naa to pa ọga rẹ ati ọmọ rẹ laarin ọjọ kan ti wọn gba a pe ko waa maa ṣe ọmọọdọ nile wọn lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2019.

Iya agbalagba ọhun, Ajọkẹ John, ẹni ọdun mọkandinlaaadọrun-un (89), ati ọmọ ẹ obinrin, Ọrẹoluwa John, ẹni ọdun mejidinlogoji (38), ni wọn jọ n gbe nile wọn to wa ni Ojule Kẹrin, Ogunlana Drive, ni Surulere, nipinlẹ Eko.

Wọn gba Joseph lati maa ri i ran niṣẹ, ṣugbọn bi ọmọkunrin to wa lati ipinlẹ Benue naa ti wọ ile ọhun, ọtọ ni ero to wa lọkan tirẹ. Bi yoo ṣe ri owo ati dukia awọn ti wọn gba a siṣẹ ko, ti yoo si sa lọ lo n ro.

Ipinnu yii lo si mu ṣẹ lọjọ keji to de ile naa gẹgẹ bii ọmọọdọ. Niṣe lo lọọ ka iya agbalagba ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin naa mọnu ile, to si fun un lọrun pa ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ. Lẹyin eyi lo mu ọbẹ, to si lọọ gun ọmọ iya yii, Ọrẹoluwa, pa mọnu yara tiẹ naa. Lo ba ko foonu, kaadi ATM, tẹlifiṣan atawọn nnkan mi-in to ji ko ninu ile naa sinu mọto awọn oloogbe ọhun, o fẹẹ maa sa lọ ni nnkan bii aago meji oru.

Ọwọ pada tẹ ọmọkunrin naa, latigba naa ni ọrọ naa ti wa nile-ẹjọ.

Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Modupẹ Nicole-Clay, ṣalaye pe gbogbo ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ ti fidi ẹsun ti wọn fi kan ọdaran naa, iyẹn idigunjale ati ipaniyan mulẹ. O ni Joseph funra ẹ jẹwọ pe oun nikan loun n gbe pẹlu awọn oloogbe, ati pe oun nikan naa lọrọ ọhun ṣoju ẹ.

Adajọ ni, “Niṣe lo fun iya agbalagba yẹn, Adejọkẹ, lọrun pa, to si gun ọmọ rẹ, Ọrẹoluwa, lọbẹ pa ni tiẹ. Pẹlu bi awọn agbẹjọro olujẹjọ ko ṣe ta ko ọrọ yii, o daju pe loootọ ni ọdaran yii ṣe nnkan to sọ yii. Bẹẹ ni mo tun ti ṣagbeyẹwo ẹri ti ọdẹ to n ṣọ ile naa, ati ti ọkunrin ọlọkada kan, ọkunrin kan to n jẹ Yahya Ibrahim, obinrin ọmọọdọ ile wọn, ati eyi ti ọga ọlọpaa naa mu wa.

“Olujẹjọ ko le ṣalaye ohun to n fi gbogbo awọn nnkan to ji gbe yii ṣe nibi ti wọn ti ka a mọ ọn lọwọ ni nnkan bii aago meji oru tọwọ ba a. Ile-ẹjọ yii ri i pe Ọgbẹni Joseph Ogbu jẹbi ẹsun iwa ika ati ipaniyan ti wọn fi kan an, fun idi eyi, ile-ẹjọ yii pa a laṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun ọ titi ti ẹmi rẹ yoo fi bọ lara rẹ. Ki Oluwa ko ṣaanu fun ọ”.

Bo tilẹ jẹ pe ọdaran ọhun n rawọ ẹbẹ pe ki ile-ẹjọ ṣiju aanu wo oun, ti Moses Enema, ti i ṣe agbẹjọro rẹ naa si n ṣe bẹẹ pẹlu bo ṣe n rọ ile-ẹjọ pe ki wọn jọwọ, ṣiju aanu wo onibaara oun ninu idajọ rẹ, amọ aṣoju ijọba ni kootu, Ọlanrewaju Daud, rọ adajọ lati dajọ olujẹjọ gẹgẹ bii ẹsun ti wọn ka si i lọrun.

 

Leave a Reply