Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Ekiti, to wa l’Ado-Ekiti, ti paṣẹ pe ki wọn so ọmọ ọdun mejilelogun kan, Kẹhinde Ọlajide, rọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.
Bakan naa nile-ẹjọ yii tun paṣẹ pe ki awọn mẹta mi-in Kareem Azeez, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Bamisile Lateef, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Adebayọ Baṣiru, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ti wọn fẹsun kan pe wọn jọ jale ọhun maa lọ sile wọn layọ atalaafia.
Ọlajide pẹlu awọn mẹta naa ni wọn fẹsun kan pe wọn ṣẹ ẹṣẹ yii lọjọ kọkanlelogun, oṣu kejila, ọdun 2019, nigba ti wọn gbimọ-pọ, ti wọn si dihamọra pẹlu ibọn ati awọn nnkan ija oloro mi-in lati ja awọn mẹrin kan lole.
Gẹgẹ bo ṣe wa lakọọlẹ iwe idajọ, awọn ti wọn ja lole ọhun ni Dayọ Fọlọrunṣọ, Saka Yusuf, Adeoye Oluwatosin, Adeọla Oluwatobi, Olayemi Are my Hambali Ojo ati Ayọdele Oluwafẹmi, ti wọn si gba awọn dukia olowo iyebiye loriṣiiriṣii lọwọ wọn.
Lara awọn dukia naa ni foonu alagbeeka olowo nla, ọkọ bọginni Lexus 350, kaadi ipe ti wọn ko ti i lo, aago ọwọ, ọkọ ayọkẹlẹ Akira kan, awọn ohun ẹṣọ olowo iyebiye, ọkada tuntun, ati owo to to ẹgbẹrun lọna igba naira.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Lekan Ogunmoye, sọ pe o han kedere pe loootọ niwa ọdaran ti wọn fẹsun rẹ kan afurasi naa ṣẹlẹ loootọ.
O ni ọdaran ki-in-ni ti orukọ rẹ n jẹ Kẹhinde Ọlajide ni ki wọn lọọ yẹ igi fun titi ti yoo fi ku, ki Ọlọrun fori ji oku rẹ.
Ọlajide ni adajọ yii ti kọkọ ran an lẹwọn oṣu mẹwaa, pẹlu alaye pe o jẹbi ẹsun kẹsan-an ninu mọkanla ti wọn ka si i lẹsẹ, o si fun un ni aye lati san owo itanran ẹgbẹrun lọna ogun naira.
Bakan naa l’Adajọ Ogunmoye fi kun un pe ko si ẹri to daju lati ṣedajọ awọn afurasi ọdaran mẹta to ku, tori naa, ki wọn maa rele wọn.