Tọpẹ Alabi sọrẹnda, o tọrọ aforiji lori ọrọ to sọ nipa orin ‘Oniduuro Mi’

Faith Adebọla 

Boya awuyewuye to n lọ nigboro lori ọrọ abuku ti gbajugbaja onkọrin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi, sọ si Adeyinka Adesioye tawọn eeyan mọ si Yinka Alaṣeyọri, lori orin ‘Oniduuro Mi’ tọmọbinrin naa kọ, yoo kasẹ nilẹ pẹlu bi Tọpẹ Alabi ṣe tuuba, o loun tọrọ aforiji lori iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade kan tobinrin naa fi lede lori iṣẹlẹ ọhun, o sọ pe:

“Mo fẹẹ gba pe loootọ ni mo ṣaṣiṣe, aṣiṣe mi si ni pe ọrọ to yẹ ki n sọ ni kọrọ ni mo sọ ni gbangba, mo tọrọ aforiji fun aṣiṣe yii, ẹ ma binu.

Nigba tọrọ yii ṣẹlẹ, mi o fẹẹ da si awuyewuye to n lọ lori orin ẹmi “Oniduuro Mi” tori mo ti ba ọpọ awọn tọrọ kan sọrọ lawọn ibi ayẹyẹ kan ta a ti pade, ṣugbọn mo ri i pe eruku ọrọ yii ko ni i rọlẹ bọrọ pẹlu bawọn oniroyin ori ẹrọ ayelujara ṣe n ku elubọ ẹ kiri.

“Ẹ jẹ ki n fi ye yin pe Tọpẹ Alabi, Adeyinka Adesioye ti inagijẹ rẹ n jẹ Alaṣeyọri ati Tolu Adelẹgan, ọmọ ẹgbẹ akọrin ẹmi kan naa ni wa, ara idile Ọlọrun kan naa la ti jade wa.

“Ọmọ mi ninu iṣẹ Oluwa ni Adeyinka. Pasitọ ẹ ni ki n gbadura fun un tori o forin kikọ jọ mi, mo si fi tinutinu ṣe bẹẹ. Ṣe mo waa fẹẹ maa jowu ẹ ni? Laye nbi kọ. Mo fẹran ọmọbinrin naa gidi. Oun naa si le sọ fun un yin, pe emi atoun jọ maa n lajọṣe daadaa. Ọlọrun ti fun awa mejeeji ni ẹbun ẹmi ati oore-ọfẹ lati de ibi ti a ba fẹẹ de, oju ọrun si to ẹyẹ i fo lai fara kanra.

“Awọn eeyan ti fẹẹ fi ipe lori foonu pa mi lori ọrọ yii, bẹẹ lawọn mi-ni tori ẹ ṣabẹwo si mi, titi kan awọn pasitọ, lati ọjọ Aje titi dasiko yii. Bi mo ṣe n sọrọ yii, awọn pasitọ kan ti wa lọna, wọn maa too debi, mo si gbagbọ pe ọrọ yii naa ni wọn fẹẹ tori ẹ dide. Oriṣiiriṣii amọran ati ọrọ lo n rọjo sọdọ mi, debii pe mi o le sun oorun asunwọra latigba tọrọ yii ti ṣẹlẹ. Bi mo ṣe n da awọn ololufẹ mi lohun lori foonu ati ẹrọ ayelujara lọsan-an, bẹẹ lawọn ololufẹ wa niluu eebo ko jẹ ki n gbadun loru, ori ọrọ yii naa si ni.

“Mi o ki i ṣe ẹni pipe o, Ọlọrun ṣi n mọ mi lọwọ bii amọkoko ni. Mo fẹ kẹyin eeyan ri mi pe eeyan ẹlẹran ara lemi naa, mo ni ibi ti mo ku si, mo si lawọn aleebu temi, koda mo ṣi n kọ ẹkọ mọ ẹkọ nipa ọgbọn Ọlọrun ti ko lopin ni.

Sista Tolu Adelẹgan ki i ṣe obinrin ti mo le tẹmbẹlu ẹ rara. Adeyinka, bi mo ṣe sọ lẹẹkan, ọmọ mi ninu iṣẹ Oluwa ni, gbogbo wa la mọyi ara wa lẹnikin-in-ni keji, ko si si ohun to le ya wa. Kurukuru lasan lọrọ yii, o maa poora lọgan.

“Ẹrin pa mi nigba ti mo ri i bawọn alawada kan ṣe sọ ọrọ naa di apara. Ẹrin ṣi n pa mi bi mo ṣe n ranti awọn fidio ti mo ti wo lori ọrọ yii, mo ṣẹṣẹ wo awọn kan tan laaarọ yii ni. Haa, awọn eeyan lọgbọn o, iṣẹ ọpọlọ gbaa ni, tori wọn mọ bi wọn ṣe le mu awada jade laarin ọrọ gidi debi to jẹ pe ọlọrọ naa ko ni i mọ igba to maa bu sẹrin-in.

“Mo mọ riri gbogbo wọn pata. Heberu ori kejila, ẹsẹ ikẹrinla, ni ka maa wa alaafia, ka si maa lepa rẹ pẹlu ẹni gbogbo ninu iwa mimọ, ka baa le ri Ọlọrun. Ohun ta a gbọdọ maa ṣe niyẹn.”

Ṣaaju asiko yii ni Adeyinka funra ẹ ti sọrọ nibi ayẹyẹ ọjọọbi kan l’Ọjọruu, Tọsidee yii, pe oun o ba Tọpẹ Alabi ja lori iṣẹlẹ yii, o ni “lya wa ninu Oluwa ni Tọpẹ Alabi, ẹ jẹ ka sinmi agbaja o”. O si rọ gbogbo awọn ololufẹ rẹ lati jawọ lori ọrọ naa, o ni ki wọn jẹ ki atẹgun fẹ si i.

Leave a Reply