Adajọ ni Mr Macaroni atawọn ẹgbẹ ẹ gbọdọ fara han nilẹ-ẹjọ lọjọ keji, oṣu to n bọ

Jide Alabi

Ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii, ni wọn sun igbẹjọ ti wọn fi kan ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Debọ Adedayọ, ti gbogbo eeyan mọ si Mr Macaroni atawọn ẹgbẹ ẹ ti wọn jọ mu si.

Ẹsun idaluru, apejọpọ to lodi ati ṣiṣe lodi si ofin Korona ni wọn fi kan wọn.

Adajọ ni wọn gbọdọ ṣeleri pe awọn ko ni i dalu ru mọ, ki wọn si huwa bii ọmọ daadaa bi wọn ba gba ominira.

Lẹyin ti agbẹjọro Mr Macaroni ti wọn pe orukọ rẹ ni Damilọla ṣe oniduroo fun un tan ni wọn ṣewe beeli rẹ, ṣugbọn awọn ọlọpaa ni awọn ko ni i fi awọn yooku silẹ, afi ti wọn ba mu oniduuro wa.

ALAROYE yọ gbọ pe aṣẹ ti wa pe wọn gbọdọ fi awọn eeyan naa silẹ lọjọ Abamẹta, Satide, naa lo mu ki gbajugbaja agba agbẹjọro nni, Mike Ozekhome, atawọn lọọya mi-in to wa nibẹ duro fun wọn.

Ohun to tun fa wahala lasiko ti wọn n yanju beeli wọn yii ni bi awọn yooku ti wọn jọ ko pẹlu Mr Macaroni ko ṣe ni fọto pelebe ti wọn yoo lẹ mọ iwe ti wọn fi gba beeli wọn, niori wọn ni eleyii pọn dandan ki wọn too le jade kuro ni agọ ọlọpaa Panti naa.

Afigba ti wọn lọọ gbe onifọto kan wa lati waa ya awọn eeyan naa ni wọn too le fi wọn silẹ. Bẹẹ ni wọn fi dandan le e pewọn gbọdọ lọọ ṣe ayẹwo arun Korona, ki wọn si mu esi rẹ lọwọ ti wọn ba n bọ nile-ẹjọ lọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii.

Leave a Reply