Adajọ ti ju Dayọ to fi tirela paayan n’Ileṣa sẹwọn 

Florence Babaṣọla

Adajọ ile-ẹjọ Majiareeti kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi ọmọkunrin awakọ tirela kan, Obilọmọ Dayọ, pamọ ṣogba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo tun fi waye lori ọrọ rẹ.

Dayọ, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ni wọn fẹsun kan pe o fi ọkọ tirela rẹ ṣeku pa Sulaiman Adebiyi lọjọ kọkanla, oṣu kejila, ọdun 2020, loju-ọna Ilesha si Akurẹ.

Gẹgẹ bi agbefọba, Jacob Akintunde, ṣe sọ ni kootu, olujẹjọ tun ba bọọsi Toyota Hiace kan jẹ lọjọ naa, to si fa sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ fawọn onimọto ti wọn gba oju-ọna lọjọ naa.

Akintunde ṣalaye pe iwa ti olujẹjọ hu ọhun lodi, bẹẹ lo si nijiya labẹ ipin ikẹrindinlaaadọjọ [146] abala ikejidinlogun ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Nigba ti wọn ka ẹsun maraarun-un ti wọn fi kan olujẹjọ fun un, o ni oun ko jẹbi wọn. Bakan naa ni agbẹjọro rẹ, K. Nwoke, bẹbẹ fun beeli rẹ lọna irọrun, ṣugbọn agbefọba ta ko ẹbẹ Nwoke.

Ninu idajọ rẹ, Majisreeti Adekanmi Adeyẹba paṣẹ pe ki wọn lọọ fi olujẹjọ sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọgbọnjọ, oṣu keje, ọdun yii, tigbẹẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.

 

Leave a Reply