Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Olowoṣọla Femi Abiọdun, ati Olowoṣọla Sunday toun jẹ ẹni ọdun marundinlogoji, nile-ẹjọ giga ilu Ado-Ekiti ti ni ki wọn lọọ yẹgi fun titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.
Awọn eeyan naa ni wọn sọ pe wọn ja ileepo kan lole niluu Ikọle-Ekiti lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2017.
Amofin Julius Ajibare to ṣoju ijọba fẹsun kan wọn pe wọn gbe ibọn lọọ ka Awoyọmi Temitọpẹ mọ ileepo to ti n ṣiṣẹ, wọn si gba miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (N1.3m) pẹlu foonu Tecno L8 meji ati Nokia kan.
O ni ẹsun mẹta lawọn olujẹjọ naa jẹbi wọn, iyẹn igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi, idigunjale ati nini ibọn nikaawọ lọna aitọ.
Temitọpẹ ti wọn ja lole sọ fun kootu naa pe oun ni manija ileepo ọhun, bi awọn adigunjale naa si ṣe de ni wọn fi ibọn gba oun lori, ki wọn too gba owo ati foonu lọ.
Amofin Ajibare pe awọn ẹlẹrii mẹta lati fidi awọn ẹsun rẹ mulẹ, bẹẹ lo lo akọsilẹ awọn olujẹjọ, ibọn meji, ọta mẹta atawọn foonu mẹtẹẹta ti wọn ji gẹgẹ bii ẹri.
Amofin Yinka Ọpaleke lo ṣoju awọn olujẹjọ, ṣugbọn ko pe ẹlẹrii kankan.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidaajọ Adekunle Adelẹyẹ sọ pe awọn nnkan ti wọn ba lọwọ awọn eeyan naa ati ẹri to wa nilẹ ta ko wọn ni gbogbo ọna, o si fi han pe wọn digun jale loootọ.
O waa ni ki wọn lọọ yẹgi fun wọn lori ẹsun kin-in-ni ati ekeji, ki wọn si lọọ ṣẹwọn ọdun mẹwaa lori ẹsun kẹta.