Adajọ ti ni ki wọn yẹgi fun Ademọla to pa ẹgbọn rẹ nitori ogun baba wọn ni Usin-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjo giga kan nipinlẹ Ekiti, ti paṣẹ pe ki wọn so ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlaaadọta kan, Akinọla Ademọla, soke titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ.

Ile-ẹjọ ti Onidaajọ Lekan Ogunmoye n ṣe akoso rẹ ni wọn gbe Ademọla lọ ninu oṣu Kejila, ọdun 2020, lori ẹsun idigunjale ati pipa ẹgbọn rẹ.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun ti wọn fi kan Ademọla ṣe sọ, wọn ni o ja ẹgbọn rẹ, Tunde Akinọla, lole lẹyin to gba ẹmi rẹ, o si gbe ọkada rẹ ti nọmba idanimọ rẹ jẹ EKITI, ADK, 011 VC  lọ.

Lakooko idigunjale naa, ọdaran yii ni ko oun ija oloro bii ibọn, ọbẹ ati oun ija miiran dani lati lọọ dena de ẹgbọn rẹ loju ọna to lọ si oko wọn.

Ẹnikan torukọ rẹ njẹ Anikẹ Ogunnusi, to waa jẹrii nile-ẹjọ lakooko ti igbẹjọ naa nlọ lọwọ ṣalaye pe lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, oun ati oloogbe naa lawọn n lọ soko pẹlu ọkada rẹ. O fi kun un pe bi awọn ṣe n lọ lawọn de ibi kan to ni koto loju ọna naa, oun si bọ silẹ lati fi ẹsẹ rin siwaju.

O ni sadeede loun ri Ademọla pẹlu ibọn nibi to fara pamọ si lẹbaa igbo. Ogunnusi ni eyi lo fa a ti oun fi pariwo, ti oun si kigbe pe “Tunde, Tunde, sare, eeyan kan fẹẹ yinbọn, o ni ṣugbọn ki oun too pariwo tan ni ọdaran naa ti yinbọn si ẹgbọn rẹ, ti oun naa si sa gba ọna miiran lọ.

O ṣalaye pe bi oun ṣe sa siwaju diẹ ni oun ri ẹnikan, oun si ṣe gbogbo alaye ohun to ṣẹlẹ fun un, to si mun oun pada si ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ. Ṣugbọn bi wọn se debẹ, oloogbe naa ni wọn ba ninu aporo ẹjẹ, to si ti jẹ Ọlọrun nipe, wọn si ti gbe ọkada rẹ lọ.

 

Bakan naa ni ẹlomiiran to waa jẹrii lakooko igbẹjọ naa tun ṣalaye pe oloogbe naa ati aburo rẹ yii ni wọn ti n ja lati igba diẹ lori oko ati dukia miiran to jẹ ti baba wọn to doloogbe.

Lakooko itọpinpin awọn ọlọpaa, wọn ba ọkada oloogbe yii ni nile aburo rẹ yii, o ti paarọ nọmba rẹ, ṣugbọn awọn ọlọpa ṣi da a mọ pẹlu nọmba idanimọ to wa lori ẹrọ ọkada naa.

Lati fi idi ẹsun naa mulẹ, Agbefọba, Shina Adeyẹmi, pe ẹlẹrii mẹrin, bakan naa lo ko iwe ti wọn fi gba ọrọ lẹnu awọn ẹlẹrii meji to waa jẹrii nile-ẹjọ naa ati aworan ọdaran ọhun, nibi to ti fi ọkada oloogbe naa ya fọto ati awọn ẹri miiran.

Agbẹjọro afurasi naa, Ọgbẹni Ọlarewaju Oluwaṣọla ko pe ẹlẹrii kankan.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Lekan Ogunmoye sọ pe, “Dajudaju, ẹri wa pe ọdaran naa digun ja ẹgbọn rẹ lole ati ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an mulẹ ṣinṣin.

O ṣalaye pe agbefọba fidi rẹ mulẹ daadaa pe ọmọkunrin yii lo ṣeku pa ẹgbọn rẹ.

“Ọdaran yii ni ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun lori ẹsun idigunjale, bakan naa ninu ẹsun keji to jẹ ẹsun ipaniyan. Ki wọn so o rọ titi ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ. Ki Ọlọrun Ọba ko fori ji ẹmi rẹ.” Bẹẹ ni Adajọ Ogunmoye sọ.

Leave a Reply