Aderounmu Kazeem
Lẹyin ọdun mejilelọgbọn ti wọn ti jọ n gbe papọ, ti wọn si ti bimọ marun-un funra wọn, kootu kọkọ-kọkọ kan ti tu igbeyawo wọn ka nipinlẹ Ekiti.
Arabinrin Yẹmisi Ojo ti paṣẹ fun tọkọ-tiyawo yii, Ọgbẹni Ọladiipọ Ogunlẹyẹ, ẹni ọdun mọkanlelọgọta, to n ṣiṣẹ mẹkaniiki ati iyawo ẹ, Adeọla Falade, ki wọn fopin si ibagbepọ lọkọ-laya ti wọn n ṣe pelu ara wọn, nitori ko si ohun to jẹ mọ igbeyawo kan bayii laarin awọn mejeeji.
Aarẹ ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ yii tun sọ pe, ohun mi-in to mu oun fagi le ibaṣepọ wọn ni pe iyawo naa, Adeọla Falade, to jẹ oṣiṣẹ ijọba ti sọ nile-ẹjọ pe, niṣe ni ọkunrin naa maa n lu oun lọpọ igba, to si maa n le oun kiri adugbo.
O ti waa paṣẹ fun obinrin yii pe o gbọdọ maa fun awọn ọmọ to bi fun Ogunlẹyẹ lanfaani lati maa wa baba wọn lọ, paapaa lasiko ti wọn ba wa nisinimi ọlude. Bẹẹ ni Ogunlẹyẹ paapaa gbọdọ maa sanwo ileewe awọn ọmọ ẹ deede.
Bẹẹ lo rọ awọn mejeeji lati gba alaafia laye, ki enikẹni ninu wọn ma ṣe tapa si idajọ ile-ẹjọ, ki wọn ma baa foju wina ofin.
Ọkunrin mẹkaniiki yii ti sọ ki wọn too tu wọn ka pe gbogbo ojuṣe to yẹ loun n ṣe tẹlẹ, ṣugbọn ni kete ti iyawo oun ti fi oun silẹ loun ko ti ṣe e mọ.