Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, ti ṣapejuwe iku Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, gẹgẹ bii adanu nla fun iran Yoruba.
Oluwoo, ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibrahim, fi sita sọ pe opin iran kan ni iku Alaafin nitori o jẹ ọba to ni ifẹ ati ọwọ nla fun iran Yoruba.
O ni, “Mo ṣabẹwo si Baba Alaafin lọsẹ to kọja, nigba ti ọkan mi fa si i. A sọrọ bonkẹlẹ to dara pupọ. Inu awa mejeeji dun, mo si mu ninu omi ọgbọn baba. A tun fẹnuko lati pade nibi eto kan ti yoo waye loṣu Karun-un, nipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn o jọ mi loju lati gbọ nipa iku baba laaarọ yii, ṣugbọn ta lo le ba Ọlọrun wijọ?
“Iku Alaafin, Ọba Adeyẹmi, jẹ adanu nla fun iran Yoruba. Alafo to fi silẹ yoo nira lati di. Ẹni takuntakun, oloootọ eniyan, baba to n ṣojuṣe rẹ bo ṣe tọ fun ilẹ Yoruba si ni pẹlu.
“Titi laelae ni n o maa fọnrere awọn aṣeyọri Alaafin. Ifẹ rẹ ati ọwọ to ni fun iran Yoruba ko ṣee fẹnu sọ. O sin ilẹ yii tọkantọkan titi doju iku.
“Mo gbadura pe ki Ọlọrun fun ọ nisinmi, ko si dari gbogbo aiṣedeede rẹ ji ọ. Mo tun ba gbogbo idile Adeyẹmi, awọn Ọyọmesi, ilu Ọyọ, ipinlẹ Ọyọ ati gbogbo ọmọ Naijiria daro.”