Adebiodu di ọba tuntun l’Ajasẹ-Ipo

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Olupo tilu Ajaṣẹ-Ipo, nipinlẹ Kwara, Ọba Ismail Yahaya Alebiosu ti ṣeleri igba ọtun fun awọn eeyan ilu rẹ, bẹẹ lo ni oun ko ni i ja wọn kulẹ nigba kọọkan. O ṣeleri pe ohun ti yoo maa mu ilọsiwaju ba ilu naa ni yoo jẹ oun logun. Olupo sọrọ yii lasiko ti wọn n fun un niwee-ẹri gẹgẹ bii ọba ilu naa tuntun.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nijọba ipinlẹ Kwara, latọwọ Kọmisanna to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati lọba lọba, Aliyu Saifudeen, buwọ lu Ismail Yahaya Alebiosu gẹgẹ bii Olupo ti ilu Ajasẹ-Ipo tuntun.

Kọmiṣanna sọ pe, awọn yan Ismall Yahaya Alebiosu gẹgẹ bii Olupo, nitori oun lo tọ si ipo naa. O fi kun un pe gomina fọwọ si iyansipo rẹ, ti yoo si maa ṣe atilẹyin fun un nigbakugba ti ọba alaye naa ba nilo iranlọwọ ijọba.

Nigba ti Ọba Alebiosu n tẹwọ gba iwe iyansipo rẹ, o dupẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, fun bo ṣe tẹle ohun ti awọn araalu n fẹ, to si buwọ lu iyansipo oun, o waa jẹjẹẹ pe oun ko ni i kuna lati maa ṣe ojuse oun, bẹẹ lo ṣeleri pe oun ko ni i ja awọn eeyan ilu naa kulẹ nigba kankan.

 

Leave a Reply