Florence Babaṣọla, Oṣogbo
O ṣee ṣe ki ẹjọ tijọba apapọ orileede wa n ba oludasilẹ ileetura Hilton Hotel and Resorts to wa niluu Ileefẹ, Dokita Ramon Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ ṣe lori iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, pada sipinlẹ Ọṣun bayii.
Eleyii ko ṣẹyin bi ijọba orileede wa ṣe kọwe si kootu ilu Abuja lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe oun ti jawọ ninu ẹjọ naa.
Awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfẹẹfa tijọba apapọ tun yọ ọwọ lọrọ wọn ọhun ni Adedeji Adeṣọla, Magdalene Chefunna, Adeniyi Aderogba, Oluwale Lawrence, Oyetunde Kazeem ati Adebayo Adekunle.
A oo ranti pe Agbẹjọro Fẹmi Falana (SAN) ti kọwe sijọba orileede yii lọjọ kẹrin, oṣu yii, pe ki ẹjọ naa kuro niluu Abuja wa sipinlẹ Ọṣun tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, o ni kijọba gbe ẹjọ naa le amofin agba ati kọmiṣanna fun eto idajọ nipinlẹ Ọṣun lọwọ.