Ademọla Adeleke balẹ sipinlẹ Ọṣun, o ni ki  Oyetọla maa palẹ ẹru rẹ mọ l’Abere

Florence Babaṣọla

Lẹyin asiko diẹ to lo loke-okun lati fi fimọ kun imọ, Sẹnetọ Ademọla Adeleke pada sipinlẹ Ọṣun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, o si sọ pe asiko ti to fun ẹgbẹ oṣelu APC lati maa palẹ ẹru wọn mọ.

Ademọla lo dije dupo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2018, ṣugbọn tijọba bọ sọwọ Gomina Adegboyega Oyetọla lẹyin atundi ibo lawọn ijọba ibilẹ mẹrin, ti ajọ INEC si kede Oyetọla bii ẹni to jawe olubori.

Oniruuru ẹsun ni Adeleke koju nile-ẹjọ lẹyin idibo naa, titi de ori ahesọ pe oun kọ lo ni iwe-ẹri to lo lati dupo, ṣugbọn ṣe lo gba oke-okun lọ lati lọ fimọ kun imọ.

Latilu Ibadan lawọn ọmọ ẹgbẹ ti bẹrẹ si i pade rẹ lọjọ Iṣẹgun, wọn duro niluu Ikire, Gbọngan, Akoda ati bẹẹ bẹẹ lọ, titi to fi de sẹkiteriati ẹgbẹ naa lagbegbe Biket, niluu Oṣogbo.

Ninu ọrọ rẹ, Ademọla Adeleke sọ pe ṣe loun wa lati waa mu ki awọn ọna to ti wọ gun nipinlẹ Ọṣun, oun si ti ṣetan lati da ogo ipinlẹ naa pada laipẹ ọjọ rara.

O ni gbogbo wahala keekeeke to wa ninu ẹgbẹ PDP l’Ọṣun ni yoo dohun igbagbe laipẹ, o si rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati mọ pe ninu iṣọkan nikan ni aṣeyọri wọn lọdun to n bọ wa.

O sọ siwaju pe ki Gomina Oyetọla mọ pe asiko ti to, ilẹ ti mọ, imọlẹ si ti de, o ni ko ma wulẹ daamu fi owo rẹ ṣofo, ṣe ni ko bẹrẹ si i kọ iwe idagbere bayii (Handover notes).

Ninu ọrọ ikini ku aabọ rẹ, Alaga ẹgbẹ PDP l’Ọṣun, Ọnarebu Sunday Bisi, ki Ademọla Adeleke kaabọ sipinlẹ Ọṣun, o ni oun mọ pe akanda ẹda kan ti ko ṣee ba fori gbari ni ọkunrin oloṣelu naa.

Bisi ni ipa takuntakun ni Ademọla n ko lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu PDP nigba ti ko si nile gan-an, eleyii to si fi i han gẹgẹ bii ẹni to nifẹẹ itẹsiwaju ni gbogbo ọna.

Leave a Reply