Ademọla Adeleke jawe olubori ni wọọdu rẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oludije funpo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ademọla Adeleke jawe olubori ni wọọdu rẹ. Ibo rẹ tayọ ti gbogbo awọn oludije yooku.

Ni adugbo Abogunde/Sagba, niluu Edẹ lo ti dibo ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ aarọ.

Ibo igba ati mejidinlogun lo ni, nigba ti ẹni to jẹ alatako rẹ ninu ẹgbẹ APC ni ibo mẹtalelogun pere, ti ọmọ ẹgbẹ Accord si ni ibo ẹyọ kan.

Leave a Reply