Adẹrin-in-poṣonu, Cute Abiọla, ti gbapo oṣelu ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọkan ninu awọn adẹrin-in poṣonun ilẹ wa to jẹ ọmọ bibi ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, Abdulgafar Ahmed Abiọla, ti gba iṣẹ tuntun bayii o. Iṣẹ oṣelu ni iṣẹ to gba naa. Gomina ipinlẹ Kwara, Abdul Rahman AbdulRazaq, ti fi i ṣe ọkan ninu awọn oludamọran pataki rẹ lori ọrọ to ba jẹ mọ iṣẹ ọna, iyẹn Special Assistant on Creative Industries. Ninu ẹ ni awọn oṣere, awọn apanilẹrin-in, awọn to n ṣiṣẹ ọwọ to jẹ mọ ọna ati bẹẹ bẹẹ lọ wa.

Lori ikanni to jẹ ti ijọba ipinlẹ Kwara lori Instagraamu ni wọn gbe aworan ọmọkunrin to ti kọṣẹ ologun oju omi pari yii ati gomina Kwara si, ti wọn bọ ara wọn lọwọ.

Latigba naa ni awọn eeyan ti n ki ọmọkunrin naa ku oriire ipo tuntun to ṣẹṣẹ gba yii.

Leave a Reply