Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Adewale Ẹlẹṣhọ, Aarẹ ẹgbẹ oṣẹre ANTP, lo sọrọ kan laipẹ yii pe ki Princess to pe Baba Ijẹṣa lẹjọ lori ọmọde ti wọn lo ba ṣe aṣemaṣẹ, foriji i. Ko ro ti atẹyinwa, ko si jẹ kọrọ naa tan. Ṣugbọn bi Ẹlẹṣọ ṣe sọrọ yii lawọn eeyan han an pọnkan lori ẹka Fesibuuku, wọn ni ko tilẹ ri ohun to sọ naa sọ rara, nitori ọrọ ko gba apa ibẹ yẹn lọ.
Ẹlẹṣọ ti wọn tun n pe ni Ẹnu-n ja-waya, ṣalaye pe yoo dara bi Princess ba le foriji Baba Ijẹṣa, ko ma jẹ ki nnkan mi-in tun ṣẹlẹ lori ọrọ yii mọ. Bakan naa lo bẹ ọga ọlọpaa Eko lati ṣewadii daadaa, o ni ki Gomina Sanwo-Olu paapaa ran Baba Ijẹṣa lọwọ ninu wahala yii.
Ohun ti Aarẹ ANTP naa sọ yii ni ọpọ eeyan to wo fidio naa ta ko, ti wọn ni ṣe Ẹlẹṣọ ko mọ pe Princess funra ẹ le pada ni awọn ẹjọ kan ti yoo ro lori iṣẹlẹ yii ni.
Wọn ni Princess kọ lo ni ẹjọ naa mọ, o ti di tijọba Eko pẹlu Baba Ijẹṣa. Ohun ti ofin ba si la kalẹ ni wọn yoo fi dajọ, Princess ti Ẹlẹṣọ n bẹ si kọ ni lọọya, oun kọ ni adajọ ti yoo da ẹjọ ọhun, wọn ni ohun ti ẹbẹ Ẹlẹṣọ ko fi nitumọ niyẹn.
Awọn mi-in tilẹ sọ pe ṣebi Ẹlẹṣọ ni Aarẹ ANTP ti Baba Ijẹṣa jẹ ọkan lara wọn, wọn ni ki lo n wo lati ọjọ yii ti ọmọ ẹgbẹ rẹ ti wa latimọle, to lo to ọgbọn ọjọ nibẹ ti Aarẹ ẹgbẹ ko sọrọ. Igba ti wọn ti waa fun un ni beeli tan ni Ẹlẹṣọ ṣẹṣẹ waa jade to n bẹ Princess, wọn ni ohun ti ko le mu eso kankan jade ni baba naa n sọ.
Ṣugbọn awọn mi-in naa kin Ẹlẹṣọ lẹyin, wọn ni ko buru bo ṣe sọrọ, wọn ni a ki i gbọ buburu lẹnu abọrẹ, ohun to yẹ ki olori ẹgbẹ wi naa ni Baba Dammy wi yẹn.
Awọn wọnyi sọ pe ẹbẹ la n bẹ oṣika ni Ẹlẹṣọ fi ọrọ naa ṣe, lo jẹ ko maa bẹ Princess, wọn ni ki ohun gbogbo le daa naa ni.