Adeyinka yoo ṣẹwọn ọdun mejidinlogun niluu oyinbo, nitori ọmọ kekere to n ba lo pọ

  Ọkunrin tẹ ẹ n wo yii, Adeyinka Oluwaṣeyi Ajọṣẹ, ti bẹrẹ ẹwọn ọdun mejidinlogun (18) bayii ni United Kingdom. Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni bayii (64), nigba ti yoo ba si fi jade lẹwọn naa, yoo ti pe ẹni ọdun mejilelọgọrin (82). Ọmọ ti ko ti i pe ọdun mẹtala to ti n ba sun tipẹ lo fa a, bọwọ palaba ṣe ṣegi ni wọn fọpa wọn ẹwọn fun un.

Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹfa yii, ni kootu Croydon Crown, ni U.K, ju baba ilu oyinbo yii sẹwọn, lẹyin ti gbogbo ẹri ti foju han pe niṣe lo n ba ọmọbinrin tọjọ ori ẹ ko ju mejila lọ lo pọ, o si ti ṣe kinni naa lọpọ igba fọmọ ọhun kaṣiiri too tu loṣu kọkanla, ọdun 2020.

 Ọmọ ti Ajọsẹ n ba sun naa lo lọọ sọrọ ẹ fawọn ọlọpaa, to sọ bi ọkunrin naa ṣe maa n fipa ba oun lo pọ nitori o lanfaani lati maa wa nitosi oun nile kan to wa ni Addington, U.K.

Awọn ọlọpaa bẹrẹ si i ṣọ Ajọsẹ, wọn si ri i mu lọjọ kẹtala, oṣu kọkanla, ọdun 2020.

Oun naa jẹwọ fun wọn pe loootọ loun ti sọ ọmọde ọhun di obinrin, ati pe oun maa n ba a lo pọ ti kinni ba ti wu oun i ṣe.

Fun iwa aitọ ati ifiyajẹni to foju ọmọ naa ri, kootu paṣẹ ẹwọn ọdun mejidinlogun fun baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọta naa. Iyẹn ni pe kawọn ẹbi rẹ to n pe e  ni baba ilu oyinbo ma reti rẹ nile kia.

Bi ko ba ku sẹwọn, Adeyinka Oluwaṣeyi Ajọsẹ yoo pe ẹni ọdun mejilelọgọrin (82) ko too foju kan ita.

 

Leave a Reply