Adigunjale kọ lẹta si wọn l’Ọfatẹdo, wọn ni ki wọn san ogun miliọnu ti wọn ko ba fẹẹ gbalejo ọran 

Florence Babaṣọla

Inu ibẹru-bojo lawọn eeyan agbegbe Ọlọfa Estate, Ọfatẹdo, nipinlẹ Ọṣun, wa bayii latari lẹta kan ti awọn adigunjale fọn kaakiri agbegbe naa.

Ninu lẹta naa to tẹ ALAROYE lọwọ ni awọn adigunjale naa ti sọ pe awọn n bọ waa ba awọn eeyan naa lalejo tija-tija, wọn ni ko sẹni to le di awọn lọwọ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn ni ọna kan ṣoṣo tawọn araadugbo naa le fi bọ lọwọ wahala naa ni ki wọn da miliọnu lọna ogun naira, ki wọn si ko o si ọwọ alaga adugbo wọn.

Wọn ni ọwọ alaga naa lawọn yoo ti gba owo ọhun lọjọ tawọn ba wa, lai ṣe bẹẹ, gbogbo ile lawọn yoo wọ, ọlọdẹ to ba si gbiyanju lati da awọn duro yoo ku iku aitọjọ.

A gbọ pe lẹta naa ti da ipaya sawọn eeyan agbegbe naa lọrun, koda, awọn kan ti n sa kuro laduugbo nitori wọn ko mọ ọjọ ti awọn alejo pataki naa yoo ya bo wọn.

Nigba to n sọrọ nipa lẹta naa, Alaabojuto ẹṣọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Oloye Amitolu Shittu, sọ pe awọn naa ti gbọ nipa rẹ ati pe digbi lawọn wa lati koju wọn lọjọkọjọ ti wọn ba n bọ.

Amitolu ṣalaye pe awọn ko ni i faaye gba ohunkohun to ba le da wahala silẹ rara, bẹẹ ni ko saaye fun awọn kọlọransi lati da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru.

O ni ki awọn araalu fọkan balẹ, ko sewu rara, nitori toju-tiyẹ ti alakan fi n ṣọri lawọn yoo wa lori ọrọ agbegbe naa.

Leave a Reply