Nitori ti wọn lu oyinbo ni jibiti, Gbọlahan atawọn meji mi-in dero ẹwọn n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti wọn ti gba gbogbo dukia ti Afọlabi Gbọlahan, Gbọlahan Sodiq Atanda ati Saheed Ayọmide Rabiu fi ọpọlọpọ ọdun ko jọ lọwọ wọn, ile-ẹjọ ti tun sọ awon afurasi onijibiti ti wọn n pe ni Yahoo mẹta sẹwọn.

Ajọ to n gbogun ti magomago owo ati iwa ibajẹ, iyẹn  Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, lo pe wọn lẹjọ si kootu  l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nitori ti wọn n lu awọn eeyan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara.

Eyi to n jẹ Gbọlahan ninu wọn l’Onidaajọ Olurẹmi Oguntoyinbo ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa laduugbo Ring Road, niluu Ibadan, sọ sẹwọn oṣu meje.

Gẹgẹ bii ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an ni kootu, wọn ni Gbọlahan lu oyinbo kan to n jẹ Brown Brain ni jibiti owo to to ẹgbẹrun kan dọla lori ẹrọ ayelujara.

Ilu Abẹokuta ni wọn ti ṣẹjọ Rabiu ati Atanda, nibi ti Onidaajọ Olurẹmi Oguntoyinbo ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ nibẹ ti fi Rabiu sẹwọn oṣu kan, to si fi ẹwọn oṣu mẹta ta Atanda lọrẹ.

Yatọ si sẹria ẹwọn ti wọn da fun awọn afurasi onijibiti wọnyi, ile-ẹjọ ni ki wọn da owo ti wọn fi ọgbọn alumọkọrọyi gba lọwọ awọn eeyan pada fun kaluku wọn. Bakan naa nile-ẹjọ gbẹsẹ le foonu olowo nla iphone ti wọn n lo fun iṣẹ jibiti wọn ọhun.

 

 

 

Leave a Reply