Faith Adebọla
Ba o rẹni fẹyin ti, bii ọlẹ la a ri, ba o rẹni gbẹkẹ le, a tẹra mọṣẹ ẹni, gẹgẹ bi ọrọ ewi atijọ kan ṣe sọ, boya eyi lo mu ki afurasi ọdaran kan ti wọn porukọ ẹ ni Kingsley Vejeta yii tẹra mọṣẹ to yan laayo, amọ iṣẹ naa ki i ṣe iṣẹ rere o, iṣẹ adigunjale ni, ibọn meje ọtọọtọ ni wọn ba nikaawọ oun nikan.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, DSP Bright Edafe, to fiṣẹlẹ yii lede fawọn oniroyin lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta yii, sọ pe o pẹ tawọn olugbe Agbarho, nijọba ibilẹ Ughelli ati agbegbe rẹ ti wa n fẹjọ sun ni teṣan pe awọn adigunjale ko jẹ kawọn gbadun, wọn lọkan wọn o balẹ lọsan-an, wọn o si loju oorun asunwọra loru, nitori awọn alọ-kolohun-kigbe ẹda wọnyi.
Eyi lo mu kawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ si i fimu finlẹ, ko si pẹ ti olobo fi ta wọn pe kokoro to n jẹfọ, idi ẹfọ lo wa, wọn lagbegbe naa lawọn afurasi ọhun n gbe, lawọn ọlọpaa ba bẹrẹ si i dọdẹ wọn.
Lọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, to kọja yii, lẹyin ti wọn ti ṣọ Kingsley daadaa pe o wa nile, ni DSP Habu Haman ba ko awọn ọtẹlẹmuyẹ kan sodi, pẹlu awọn ọdẹ adugbo atawọn fijilante ti wọn kun wọn lọwọ, wọn lọọ ka afurasi yii mọle rẹ to wa laduugbo Ekrerhavwe, l’Agbarho, nijọba ibilẹ ti wọn ti n ṣ’ọṣẹ kan naa yii, wọn si mu un.
Nigba tawọn ọlọpaa n fọrọ wa a lẹnu wo, o jẹwọ pe loootọ loun n digunjale, o tun lọmọ ẹgbẹ okunkun loun, amọ ki i ṣe oun nikan loun n jale ọhun, oun lawọn ikọ tawọn jọ n jade lọọ ṣe ọpureṣọn.
Wọn ni ko mu wọn lọ si ibuba wọn, o si gba lati ṣe bẹẹ, ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ keji ti wọn mu un ni wọn lọ si ibuba ọhun, amọ wọn ko ri awọn yooku ẹ nibẹ, wọn ti sa lọ, ibẹ ni wọn ti ba awọn irinṣẹ ti wọn n lo, ibọn pompo ati gbọọrọ oriṣii meje ni wọn ba, o loun loun ni awọn ibọn naa, pẹlu katiriiji ọta ibọn ti wọn ko ti i yin mẹrin, wọn si ba ada, aake ati oogun abẹnugọngọ nibẹ pẹlu.
Edafe ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii, wọn lafurasi naa n ran awọn agbofinro lọwọ lakata wọn to wa, bẹẹ lawọn ọlọpaa ṣi n dọdẹ awọn ẹlẹgbẹ rẹ to sa lọ, ki wọn le waa wi tẹnu wọn.